Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹsẹ̀ bodò nínú ìdíje FIFA t'ọdún 2018

Asia Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nàìjíríà pẹlu orílẹ̀-èdè mẹrin miran n lọ ṣojú Afrika nidije àgbáyé ni Russia

Nàìjíríà ti wà ni England báyìí nimura silẹ fún ìdíje pẹlu England lọjọ Abamẹta ni pápá ìṣeré Wembley ni Brent

Àwọn ìdíje Nàìjíríà to kù loṣu yìí

Nàìjíríà yoo koju Czech Republic nidije ọlọrẹsọrẹ lọjọru, ọjọ kẹfa, oṣu yii. Eyi ni idije to gbẹyin ti wọn ni ṣaaju idije ifé ẹyẹ agbaye.

Nàìjíríà yoo kọkọ pade Croatia lọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii ninu idije ifẹ ẹyẹ agbaye ninu ikọ D.

Nàìjíríà yoo koju Iceland ni ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun, oṣu yii ninu idije agbaye kan naa ki wọn to tẹsẹ kan bọ ṣokoto pẹlu Argentina lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu yii.

Abajade awọn idije yii ni yoo sọ ipele ti Naijiria yoo bọ si ninu idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: