Nigeria vs DR Congo: Eagles gbá ọ̀mì pẹ̀lú Leopard ní Pọtá

Ìkọ agbaboolu Super Eagles orílè-èdè Nàìjíríà ati akẹgbẹ wọn láti orílè-èdè DR Congo ti gba àmì ayò kọọkan nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọrẹsọrẹ
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà wà lára ipalemo ìkọ Super Eagles ṣaaju ìdíje ife ẹyẹ àgbáyé to n bò lónà ní Russia
Troost Ekong ló kọkọ jẹ́ ni iṣẹju kẹẹdogun ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà.

Ìkọ DR Congo kò fi ọwọ̀ fún ìkọ Super Eagles ti wọn sì n damu aṣọle Super Eagles títí ti adari ìdíje náà fi fún wọn ní gbé e silẹ gbá a síle ni iṣẹju kéjídínlọ́gọ́rin ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa.
Ọwọ ẹrọ ní Malongo Ngita fi gbá a wo inú àwọ̀n Nàìjíríà.
Ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọrẹsọrẹ yii ni ikẹyin ti Ìkọ Super Eagles yoo gba ki wọn to bẹrẹ imura ni pẹrẹwu de idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018.








