Mọ̀ nípa Anthony Okon Placid tó rọ́pò Benjamin Hundeyin gẹ́gẹ́ bíi Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police
Ọga agba fun ileeṣẹ Ọlọpaa, IGP Olatunji Rilwan Disu ti buwọlu iyansipo DCP Anthony Okon Placid, psc(+), mni gẹgẹ bii agbẹnusọ fun ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria.
DCP Placid, psc (+), mni, jẹ ogbotangiri ọmọ ogun ileeṣẹ ọlọpaa to ni ọpọlọpọ iriri, to si tun kawe gboye ni ẹka eto aabo lorilẹede Naijiria ati loke okun.
Wọn bíi Placid ni ọjọ kejì oṣu Keji ọdun 1970 niluu Uyo nipinlẹ Akwa Ibom, to si wa lati Mbiokporo Nsit ni ìjọba ibilẹ Nsit Ibom.
O kawe gboye ni fasiti Uyo nínu imọ nípa agbegbe, o tun ni imọ oye Masters ni Ofin lati fasiti Jos.
Placid wọle sinu ileeṣẹ Ọlọpaa ni ọdun 1996 lẹyin to pari ẹkọ ni ile ẹkọ ti Ọlọpaa to wa niluu Kano.
DCP Placid ti jẹ Ọga ni ọpọlọpọ ẹka ileeṣẹ Ọlọpaa bii agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Adamawa
DCP Anthony Placid tun jẹ ọmọ ẹgbẹ International Association of Chiefs of Police (IACP), Commonwealth Human Rights Trainer ati International Committee of the Red Cross (ICRC) Trainer.
Igbesẹ yii n waye lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu wọ aṣọ ọga agba ọlọpaa Naijiria fun Tunji Disu gẹgẹ bii adele ọga agba ọlọpaa orilẹede Naijiria tuntun.
Osu to kọja ni Disu bẹri niwaju aarẹ lera lera, o si yi sọtun yi sosi lẹyin ti Tinubu wọ aṣọ naa fun un tan.
Eyi waye lẹyin ti ọga agba ọlọpaa Naijiria tẹlẹ, Kayode Egbetokun, ti kọkọ gbe akoso ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria le Disu, lọwọ tan.



























