Omi gbé èèyàn 23 lọ ní Kenya lẹ́yìn òjò àrọ̀rọ̀dá

Oríṣun àwòrán, Reuters
Okere tan eeyan mẹtalelogun lo ti padanu ẹmi wọn niluu Nairobi, loriolẹede Kenya, lẹyin ti ojo arọrọda kan fa omiyale nibẹ.
Ọlọpaa ni ọgbọn eeyan lawọn ti doola bayii amọ omi gbe awọn mii lọ, nigba ti ina mọnamọna gbe awọn ẹlomiran.
Ijọba ti da awọn ọmọ ogun sita bayii lati doola awọn to ha sinu ọkọ wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọpọ dukia lo ti bajẹ, bẹẹ lawọn opopona kan ko ṣe e gba mọ.
Pupọ ninu awọn ọkọ ofurufu to yẹ ko balẹ siluu naa ni wọn ti dari siluu Mombasa bayii.
Ninu atẹjade kan, ọlọpaa sọ pe "Ojo arọrọda ti fa ẹkun omi, o ṣeni laanu pe eeyan mẹtalelogun lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ bayii, ọpọ dukia ti bajẹ, opopona ko ṣe e gba mọ, bẹẹ lawọn eeyan ti di alairilegbe."
Ṣaaju ni ẹṣọ alaabo kan, John Lomayan, ni oun ri ẹnikan to ha sabẹ ọkọ ayọkẹlẹ ki omi to gbe lọ lẹyin ti odo Nairobi River ya si aarin ilu.
O sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe "Mo ri ti omi n gbe lati apa oke ibẹyẹn.
"A o mọ ibi to wa, ko pẹ ti a ṣẹṣẹ ri labẹ mọto to wa tẹlẹ."
Awọn opopona to ṣe pataki ni olu ilu naa bii oju ona Mombasa, Uhuru, Kirinyaga, atawọn ọna kan ni Westlands ni omi ti gba.
Ijọba Kenya ti kilọ faraalu ki wọn sọra fun awọn agbegbe ti omi ti gba bẹẹ lawọn adoola ẹmi n ṣeranwọ fun awọn ti ọrọ naa kan gbọngbọn lati doola wọn.
Ṣaaju ni ajọ to n bojuto oju ọjọ nibẹ ti kọkọ kilọ pe ojo arọrọda yoo waye.
Wọn ni awọn odo yoo kun akunfaya titi di ọjọ kẹsan an oṣu kẹta ti a wa yii.
Ajọ naa ti sọ pe ọrọ naa yoo lagbara lawọn agbegbe ti omi sunmọ bii Central Highlands ati Lake Victoria Basin.
Ẹwẹ, ọpọ ọmọ orilẹede Kenya lo ba omi lọ lẹyin ojo arọrọda kan lọdun to kọja.



























