Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó wáyé ní Ibadan

Àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti àwòrán Tanimu Turaki

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní ìlú Abuja ti da ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party pè nù láti tako ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja tó ní kí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ilẹ̀ Nàìjíríà, Independent National Electoral Commission, INEC láti má gba àbọ̀ àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún àti Kẹrìndínlógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.

Nínú ìdájọ́ tí gbogbo àwọn adájọ́ mẹ́tẹ́ẹ̀ta ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà panupọ̀ lórí ìdájọ́ lórí ẹjọ́ tí PDP pè náà.

Ilé ẹjọ́ náà ní ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí PDP pè kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga kọ́kọ́ gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá jẹ́ ohun tó tọ̀nà.

Ilé ẹjọ́ náà ní ẹjọ́ tí PDP gbé wá pé ilé ẹjọ́ kò ní àṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ náà nítorí ọ̀rọ̀ abẹ́nú láàárín ẹgbẹ́ ni ẹjọ́ náà jẹ́ ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ ní àwọn tó pe ẹjọ́ ní àǹfàní láti pe ẹjọ́ láti bèèrè fún ẹ̀tọ́ wọn.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ ní igun Turaki lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP gbọdọ̀ san mílíọ̀nù méjì náírà fún ilé ẹjọ́ nítorí wọ́n gbé ẹjọ́ tí kò nílẹ́ wá síwájú wọn.

Ṣáájú ni àwọn adárí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní igun méjéèjì ti balẹ̀ sílé ẹjọ́ ní ]owúrọ̀ ọjọ́ Ajé láti mọ ibi tí ìgbẹ́jọ́ náà máa já sí

Kabiru Tanimu Turaki ló ṣaájú igun kan nígbà tí Abdulrahman Mohammed kó àwọn igun kejì sòdí lọ sílé ẹjọ́.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ẹ ó rántí pé ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2025 ni Adájọ́ James Omotosho ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé àjọ INEC kò gbọdọ̀ gba èsì àpérò ìpàdé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí wọ́n ṣe nígbà náà láì bá ṣe pé wọ́n tẹ̀lé òfin àti ìlànà tó yẹ.

Adájọ́ Omotosho ní INEC kò ní àṣẹ láti gba àpérò ẹgbẹ́ kankan wọlé láì bá ṣe wí pé wọ́n tẹ̀lé àṣẹ ìwé òfin ilẹ̀ wà, òfin tó de ètò ìdìbò àti òfin àti ìlànà ẹgbẹ́ wọn.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mẹ́ta tí wọ́n pe ẹjọ́ náà ní kí ilé ẹjọ́ ṣe ìdádúró àpérò náà tó wáyé ní ìlú Ibadan níbi tí wọ́n ti yan àwọn adárí tuntun fún ẹgbẹ́ náà.

Àwọn tí wọ́n pè lẹ́jọ́ ni àjọ INEC, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, akọ̀wé àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ PDP, Samuel Anyanwu, akọ̀wé adarí ètò ẹgbẹ́, Umar Bature, àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Ambassador Umar Iliya Damagum, Ali Odefa, àti Emmanuel Ogidi.