Wo tọkọtaya tó ń gba àwẹ̀ Lent àti Ramadan papọ̀
Lọdun yii, oṣu Ramadan ati oṣu awẹ Kristẹni papọ si asiko kan naa fun igba akọkọ lati ọdun 1993.
Fun ẹsin mejeeji yii asiko ifaẹnijin ati awẹ ni oṣu mejeeji yii jẹ.
NI ilu Ikorodu, awọn lọkọlaya kan wa, Ọgbẹni Ọlanrewaju Michael Williams pẹlu iyawo rẹ Kaosara Ọmọlabakẹ Williams. Kristẹni ni ọkọ, iyawo si jẹ ẹlẹsin Musulumi.
BBC News Yoruba ba ọkọ ati iyawo ti wọn jẹ ẹlẹsin ọtọọtọ yii sọrọ lori awẹ ẹsin mejeeji to parapọ n lọ lọwọ bayii.
Ninu ọrọ wọn awọn mejeeji ṣalaye pe ẹkunrẹrẹ ibukun lo ja si fun awọn lati maa gba awẹ Ramadan ati Lẹnti pọ lasiko kan naa.
Wọn ni o dara pupọ nitori pe ọkan awọn mejeeji yii papọ si ọna kan naa.
Ọgbẹni Ọlanrewaju Micheal Williams ṣalaye pe ka ni ọtọọtọ ni awẹ naa ni, o ṣeeṣe ki awẹ naa ma pe fun eyikeyi ninu wọn to ba n gba a.



