Kí ni ìyàtọ̀ ààwẹ̀ Lent àwọn Kristẹni àti Ramadan àwọn Musulumi?

Ami agbelebu ati oṣupa

Oríṣun àwòrán, GETTY

Ni 2024 yii, asiko kan naa ni aawẹ Lẹnt awọn Kristẹni ati Ramadan awọn ẹlẹsin Islam bọ si.

Ojọ kẹrinla oṣu keji ọdun yii ni awọn Kristẹni bẹrẹ aawẹ wọn ti i ṣe Lent, yoo si pari lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta yii.

Aawẹ Ramadan ọdun yii bẹrẹ lọjọ kọkanla oṣu kẹta, oun naa yoo si jẹ gbigba fun ọjọ mọkandinlọgbọn tabi ọgbọn ọjọ.

Ṣugbọn bawọn aawẹ yii ṣe wọnu ara wọn to, awọn iyatọ kọọkan wa laarin wọn.

Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí aawẹ Lent ṣe bẹ̀rẹ̀

Ogoji ọjọ ni awọn Kristẹni fi maa n gba aawẹ Lent, asiko rẹ ni wọn si maa n ranti awọn iṣẹlẹ to waye lasiko ipapoda Jesu, ẹni ti igbesi aye rẹ pada di ohun ti ẹsin Igbagbọ da le lori.

Awọn Kristẹni gbagbọ pe gbigba aawẹ yii n ṣafihan iru ifarajin ti Jesu ṣe nigba to wọnu igbo lọ lati gbadura fun ogoji ọjọ, ki wọn too kan an mọ agbelebu.

Asiko itọrọ aforoji ni,eyi tawọn Kristẹni maa n ṣayẹyẹ iranti agbelebu ninu ọdun Easter. Ipari aawẹ ni ọdun Easter maa n waye.

Ramadan

rosary

Oríṣun àwòrán, Getty

Oṣu Ramadan ni ikẹsan-an ninu oṣu oju ọrun ti awọn Musulumi maa n lo lati fi ka ọjọ. Oṣu pataki ni Ramadan ninu ẹsin Islam.

Awọn Musulumi gbagbọ pe ninu oṣu yii ni abala akọkọ Alukurani sọkalẹ fun Anọbi Mohammed (Ki ikẹ ati ọla Allah ko maa ba a).

Ninu oṣu yii ni a ti pa awọn Musulumi laṣẹ lati gbaawẹ, ṣe itọrẹ aanu, huwa daadaa sawọn eeyan ki wọn si sun mọ Ọlọrun ju ti tẹlẹ lọ.

Awọn iyatọ to wa laarin Lent ati Ramadan

owo

Oríṣun àwòrán, Getty

Ogoji ọjọ ni wọn fi n gba Lent, eyi to maa n bẹrẹ l’Ọjọru Eleeru (Ash Wednesday), yoo si pari lọjọ Aiku ti i ṣe Easter Sunday.

Aawẹ Musulumi le gba ọjọ mọkandinlọgbọn tabi ọgbọn ọjọ, bi wọn ba ṣe tete ri oṣu si ni yoo sọ ọjọ ọdun gan-an.

Kristẹni ki i gbaawẹ lọjọ Aiku, ṣugbọn aawẹ Musulumi ki i yọ ọjọ kankan silẹ, afi to ba tán.

Bí wọ́n ṣe ń gba àwọn ààwẹ̀ náà

osupa

Oríṣun àwòrán, Getty

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ ẹsin lo n gbaawẹ, ọna ti kaluku n gba gba tiẹ yatọ sira wọn.

Opo kan ninu ẹsin Islam ni aawẹ gbigba jẹ, pataki si ni nigbesi aye awọn Musulumi.

Awọn opo ẹsin Islam to ku ni nini igbagbọ ninu Ọlọrun ọkan ṣoṣo, irun kiki, Zaka yiyọ ati lilọ si Mẹka beeyan ba lagbara lati lọ.

Aawẹ Ramadan maa n jẹ kawọn eeyan sunmọ Ọlọrun si i.

Awọn Musulumi maa n jẹ saari lẹẹkan lojumọ ki ilẹ too mọ.

Bilẹ ba ti mọ, wọn o ni i jẹun, mumi tabi ṣere ifẹ mọ afi tilẹ ba ṣu, ti wọn ṣinu.

Ṣugbọn bi aawẹ ṣe jẹ dandan to fawọn Musulumi, awọn eeyan kan wa ti wọn yọnda wọn lati ma gba a.

Awọn wọnyi ni oloyun, obinrin to n fun ọmọ lọmu, obinrin to n ṣe nnkan oṣu, awọn eeyan ti ilera wọn ko pe, ti aawẹ gbigba si le fa inira fun wọn pẹlu awọn arinrinajo.

Bi aawẹ ba pari, awọn eeyan wọnyi yoo ni lati san awọn aawẹ ti wọn ko gba pada, gẹgẹ bi aṣẹ Allah, ki tiwọn naa le pe e bii tawọn eeyan yooku ti wọn gba aawẹ ọjọ mọkandinlọgbọn abi ọgbọn.

: Lasiko Lent, awọn Kristẹni maa n gbadura. Dandan ni aawẹ gbigba jẹ fawọn Kristẹni l’Ọjọru Eleeru ati ọjọ Ẹti rere (Good Friday).

Awọn ti wọn n gbaawẹ Kristẹni le jẹun lẹẹkan lojumọ.

Lẹyin Ọjọruu Eleeru ati ọjọ Ẹti rere, wọn gbọdọ maa gbaawẹ ni gbogbo ọjọ Ẹti.

Ofin ko faaye gba ẹran jijẹ, afi ẹja atawọn ẹranko mi-in ti aaye wa fun lati jẹ.

Bi aawẹ Lent ṣe n lọ lọwọ, awọn Kristẹni le maa ṣe awọn iṣẹ oloore mi-in bii Bibeli kika, lilọ si ipade adura, ṣiṣẹ itọrẹ aanu, ṣiṣe abẹwo silewosan ati ọgba ẹwọn ati sisọrọ Ọlọrun fawọn eeyan lati gbọ.