Easter Eggs: Kí ló kan Ẹyin àti Ehoro nínú ìtàn àti ayẹyẹ ọdún Àjíǹde Jésú Krístì?

rabbits-in-a-basket-surrounded-by-colourful-eggs

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun Ajinde Easter jẹ ọpọmulero igbagbọ awọn ọmọlẹyin Kristi to ti wa fun ẹgbẹgbẹrun ọdun.

Asiko ọdun Ajinde ni awọn onigbagbọ ma n ṣe ajọdun ajinde Jesu Kristi kuro ni ipo oku, ti Iwe Mimọ Bibeli sọ wipe Jẹsu Kristi ku lori igi agbelebu ni Ọjọ Ẹti rere, Good Friday.

Gẹgẹ bi bibẹli ṣe sọ, Jesu Kristi jinde ni ọjọ kẹta kuro ni ipo oku, ti o si jasi Ọjọ Ajinde.

Ni ọdọọdun, ọdun Ajinde ma n yatọ to si ṣeeṣe ko waye lọjọ kan laarin ọjọ kọkanlelogun, Oṣu Kẹta si Ọjọ karundinlọgbọn, Oṣu Kẹrin, eleyii ti awọn kan gbọgbọ wipe o niṣe pẹlu bi irawọ ba ṣe tan imolẹ si(Full Moon).

Lasiko ọdun Ajinde, awọn Kristẹni maa n darapọ lati gbadura ki wọn si jọ jẹun papọ, tori pe ṣaaju asiko naa, wọn ti wa ninu awẹ Lẹnti ogoji ọjọ gẹgẹ bi Jesu Kristi naa ṣe gba a ninu iwe mimọ.

Ki lo wa n jẹ "Ẹyin" ọdun Ajinde?

Odun Ajinde

Oríṣun àwòrán, Google

Ni Ilẹ Yuroopu, ọpọlọpọ eniyan lo maa n jẹ ṣọkoleeti ẹlẹyin lasiko ọdun Ajinde lati fi ṣe ayẹyẹ ajinde Jesu Kristi.

Ni igba ti asa ẹyin bẹrẹ, awọn adari ẹsin ni igba naa lọhun kii gba ki awọn eniyan jẹ ẹyin lasiko ọsẹ ijiya Jesu, ti awọn oloyinbo n pe ni Holy Week.

Nitori naa ohun ti awọn eniyan maa n ṣe ni lati ko awọn ẹyin ti adiye ba ye ni asiko yii pamọ, ti wọn a si ṣe e ni ẹṣọ, ti wọn a si fun awọn ọmọde gẹgẹ bi ẹbun ni ọjọ Ajinde.

Easter chocolate

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Titi di oni ni awọn eniyan ṣi n ṣe e, ti wọn si n fun awọn eniyan ni ẹbun ẹyin ni ọdun Ajinde.

"Ehoro" nkọ, kini wọn fi ṣe ni Ọjọ Ajinde?

Rabbits sitting behind some Easter eggs

Oríṣun àwòrán, iStock

Itan ehoro ajinde ni o wọpọ ni awujọ awọn eniyan ni ọdun 1900 lọhun.

Awọn ehoro maa n bi ọmọ to maa n tobi ti awọn oloyinbo n pe ni (kitten), ti awọn eniyan si ri wọn gẹgẹ bi ibẹrẹ igbe aye tuntun.

Itan sọ fun wa pe awọn ẹyin ti ehoro ba ye ni asiko yii, ehoro ma n ṣe e ni ẹsọ ti asi lọ gbe e pamọ.

Nitori naa awọn ọmọ kekeeke ma n wa ẹyin ehoro kaakiri lasiko ọdun ajinde.