Sunday Igboho gba àwọn aṣojú ìjọba Nàìjíríà tuntun sílẹ̀ òkèèrè lámọ̀ràn, Ó ní 'ẹ bá Tinubu ṣíṣẹ́ pọ̀ láti yí orúkọ Naijiria padà sí rere'

Oríṣun àwòrán, Femi Fani-Kayode/Facebook
Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti gbawọn aṣoju ijọba Naijiria silẹ okeere ni imọran wi pe ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu Aarẹ Bola Tinubu lati fun orilẹede Naijiria ni orukọ rere lawọn orilẹede ti wọn ba wa nilẹ okeere.
Igboho rọ awọn aṣoju ijọba naa ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ki wọn lo iriri wọn gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ lati ṣoju Naijiria ni orilẹede ti ijọba n gbe wọn lọ.
Owo Baba Dami gboriyin fun Tinubu lori awọn eeyan to yan sipo aṣoju Naijiria silẹ okeere naa.
Bakan naa tun ni Igboho rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati maa sọ rere nipa orilẹede Naijira, lai fi ti ẹsin, ẹya, tabi ẹgbẹ oṣelu ti wọn ba wa ṣe.
Lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, kede awọn orilẹede ti Tinubu gbe awọn aṣoju ijọba Naijiria marundinlaadọrin to ṣẹṣẹ yan sipo naa lọ.
Orilẹede Germany ni ijọba gbe minisita fọrọ ọkọ ofurufu tẹlẹ, Femi Fani Kayode, lọ, nigba ti Ọjọgbọn Isaac Adewole yoo maa ṣoju Naijiria ni Canada.
Oludamọran aarẹ Naijiria tẹlẹ, Reno Omokri, yoo ṣoju Naijiria ni Mexico, orilẹede China ni Ajagun fẹyinti Abdulrahman Dambazau n lọ ni tiẹ.
Kayode Are ni ijọba apapọ gbe lọ si orilẹede Amẹrika, nigba ti ọga agba ajọ NIA tẹlẹ, Ayodeji Oke, yoo maa ṣoju Naijiria lorilẹede France.
Igboho ni ''mo n fi asiko yii dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu lori bi o ti yan Fani-Kayode atawọn ọmọ Yoruba mii sipo aṣoju Naijiria silẹ okeere.
Nnkan to wuni lori gidi ni ohun ti Aarẹ Tinubu ṣe yii.
Bakan naa ni mo tun dupẹ lọwọ Kabiyesi Olugbon ti Orile Igbon, Oba Francis Olusola Alao ati agbẹjọro Aarẹ Tinubu, Oluwole Afolabi (SAN), lori iyansipo Fani-Kayode gẹgẹ bi aṣoju Naijiria silẹ okeere ni Germany.''



























