Osinbajo pe ìpàdé pẹ̀lú àwọn èèkàn òṣiṣẹ́ ìjọba lórí Saraki

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo/Facebook
Ìròyìn jáde pé Igbákejì Ààrẹ, Yemi Osinbajo, sọ ọ̀rọ̀ Saraki di ohun a bá jìjọ wò!
Oṣinbajo ti pe ìpàdé pẹ̀lú àwọn èèkàn òṣiṣẹ́ ìjoba láti jírórò lórí ọ̀rọ̀ Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà, Bukola Saraki.
Ìwé ìròyin kan sọ pé àwọn bíi ọ̀ga ọlọ́páà Ibrahim Idris, adarí àjọ SSS, Lawan Daura, àti agbẹjọ́rò àgba ní orílẹ̀-ede Naijiria, Abubakar Malami, ni ó wà nínú ipade náà pẹ̀lú Osinbajo tí ó wáyé ní ọsán òní (ọjọ́ Ajé).
Kò sẹ́ni tó mọ oun tí wọ́n sọ nínú ìpàdé náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìròyìn míràn fi hàn pé ọgá àgbà ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti ń wá àtìlẹ̀yìn ilé iṣẹ́ ààrẹ láti lè wọ́dìí Saraki.

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki/Twitter
Ẹ ọ rántí pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti ní àwọn fẹ́ fi ọrọ wá Saraki lẹ́nu wò lórí àwọn adigunjalè tí wọ́n mu lórí ìkọlù ti ó gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Ofa.
Saraki ti ní òun yóò jẹ́ ìpè ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá o.
Ó ní, "Mo ti sọ fún olùrànlọ́wọ́ mi pé kó gba ìwé ìpeni látọ̀dọ̀ ilé isẹ̀ Ọlọ́pàá èyí tó ní se pẹ̀lú ẹ̀sùn tí wọ́n gbé jáde lánàá kí n lè tètè jẹ́ wọn ní òo."









