Àjọ ọlọ́pàá fìwépe Bukola Saraki lórí ìdigunjalè Offa

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki/Twitter
Àjọ ọlọ́pàá orílẹ̀eèdè Naijiria ní àwọn ti fìwé pe Olórí Ilé Aṣòfin Àgbà, Bukola Saraki, láti wá sọ oun tí ó mọ̀ nípa ìdigunjálè Offa, ní Ìpínlẹ̀ Kwara nínú èyí tí àwọn ọlọ́ṣà pa ènìyàn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Oṣù Kẹrin.
Agbẹnusọ àjọ ọlọ̀paa, Jimoh Moshood, ní ó ṣe pàtàki láti fi ọrọ wá Saraki lẹ́nu wo nítori ọ̀rọ̀ tí márùń nínú àwọn adigunjalè tí ọwọ́ ti tẹ̀ sọ tí ó ta bá olóṣélú nàá.
Agbẹnusọ fun Saraki, Yusuf Olaniyonu, ní olori ile aṣòfin náà yóó fèsì lórí ẹ̀sùn tí wọn fi kàń tí àkókò bá tó.
Moshood ní àwọn márùń náà ni Ayoade Akinnibosun, Ibukunle Ogunleye, Adeola Abraham, Salawudeen Azeez ati Niyi Ogundiran.
A gbọ̀ pé ọwọ́ tẹ gbogbo àwọn afrunrasí tí ó wà ní àhámọ báyìí lẹ́hìn tí ọlọ́pàá kọ́kọ́ mú afunrasí méjì - Kunle Ogunleye àti Michael Adikwu tí fídíò ilé ìfowópamọ́sí rí ojú wọn nígbà ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Oríṣun àwòrán, PRNigeria
Moshood sọ nígbà tí òun bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí bí ìwádìí ṣe ń lọ lórí ọrọ nàà, pe afunrasí méjìlélógún ni ọwọ ti tẹ̀ báyìí o.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe àfihàn àwọn ìbọn, ọkọ̀ àti owo tí wọn rí gbà lọ́wọ́ àwọn arunrasí náà.
Gomina Ipinlẹ̀ Kwara, Abdulfatah Ahmed, wà lára àwọn tí ọ̀rọ̀ ti ta bá lórí ìdigunjalè náà. Méjì lára àwọn olùranlọ́wọ́ gómínà náà, Alabi Olalekan àti Yusuf Abdulwahab ni ọ wà ní àhámọ́ báyìí.












