Nigeria Election 2019: PDP àti SDP ìpínlẹ̀ Ọyọ fa Seyi Makinde sílẹ̀ ní olùdíje nigba ti ADC àti ZLP n ṣe ipinnu lọwọ

Àkọlé fídíò, PDP, SDP, ZLP ati ADC fa Seyi Makinde kalẹ̀

Apapọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ati Peoples Democratic Party ti fa oludije kan ṣoṣo silẹ lati ṣoju wọn ninu idibo gomina ipinlẹ Ọyọ.

Seyi Makinde
Àkọlé àwòrán, Seyi Makinde n ri atilẹyin ẹgbẹ mii, idibo Oyo n dùn síi

Eyi waye nibi ipade kan ti awọn oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta, ati awọn agbaagba ẹgbẹ ṣe nile gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Oloye Rashidi Ladọja nilu Ibadan lọjọ Abamẹta.

Awọn oludije ti iroyin ni wọn ṣi n ronu lori ipinnu wọn lọwọ ni lati fa Makinde tabi bẹẹ kọ.

Àkọlé fídíò, Yinka Ajia: ìbẹ̀rù Ọlọrun ni mo fẹ́ fi tukọ̀ Kwara ti mo ba wọlé

Ṣaaju ni iru ipade bẹ ti waye ninu ẹgbẹ All Progressives Congress, APC pẹlu ADP nipinlẹ Oyo.

Nibi ti Alao Akala si wọgile erongba rẹ lati dije fun ipo gomina ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta, to si sọ pe oludije ẹgbẹ APC, Adebayọ Adelabu l'oun yoo ṣe atilẹyin fun.

Ọpọ àwọn eniyan ipinlẹ Ọyọ lo n wo ohun ti gbogbo ifọwọsowọpọ yii ṣeeṣe ko bi fun idibo gomina nipinlẹ Ọyọ to m bọ lọna.

Àkọlé fídíò, #NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí