NBC ní kí àwọn ilésẹ to tẹ ofin lóju san #500,000

Oríṣun àwòrán, NBC
Ile ise iroyin marundinlaadota ni ajọ NBC ni ko sanwo ìtanran fún àwọn aṣe máse tó wáye lásiko ìdìbò gbogboogbo tó wáye lọ́jọ́ kẹtalélógún oṣu tó kọja.
Awọn ile iṣẹ iroyin tí igbá ọ̀rọ̀ náà kan náà ṣí mọ lóri ni Channels, TVC, NTA, AIT, Vision Fm, Arewa radio, Radio Lagos àti àwọn míràn.

Oríṣun àwòrán, Nbc

Oríṣun àwòrán, Nbc
Gẹgẹ bi olorí àjọ náà Mallam Modibo Kawu ni gbogbo àwọn ile iṣẹ́ yìí ni yóò fi ẹgbẹrun lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta naira jura.
O ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilanilọyẹ ni àjọ oun ti ṣe láti ri dáju pẹ ẹnikẹni ò tẹ ojú òfin mọ́lẹ̀, sùgbọn o ṣe ni láànú pé gbogbo rẹ̀ pàbó ló jási lásiko ìdìbọ ààrẹ tó wáye ní ọjọ kẹtàlélogun osu kéji.
O ní ẹsẹ ti àwọn ile iṣẹ yii sẹ jẹ oríṣiriṣi, sùgbọn kò kéré sí àwọn ilé ìròyìn tó wọn jẹ ki wọn fi ilé iṣẹ́ wọn tẹ́ pẹpẹ èèbu àti sisọ àwọn ọ̀rọ̀ alufansa.
O fi kún pé àwọn ile iṣẹ́ Radio mi fààyè gba ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ tó lé dá rògbòdiyàn sílẹ̀ láwùjọ.









