Nigeria Election 2019: Akala padà sí APC fún ìbò gómìnà Oyo

Alao Akala

Oríṣun àwòrán, APC

Àkọlé àwòrán, Eto idibo gomina ipinlẹ Oyo

Oludije fu ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADP Otunba Christopher Adebayo Alao-Akala ti kede pe oun ti darapọ mọ Adebayo Adekola Adelabu to jẹ oludije fẹgbẹ APC fun ibo gomina ọjọ Abamẹta ọsẹ to n bọ.

Ṣugbọn Akala ṣalaye pe oun yoo ṣatilẹyin fawọn oludije fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ ADP.

Akala ni otitọ l'oun ṣepade pẹlu awọn ẹgbẹ alatako bi PDP, ADC ati ZLP, wi pe Gomina Ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri Rashidi Ladoja lo ṣagbatẹru ipade ọhun.

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ Akala nigba ti ipade oun pẹlu ẹgbẹ awọn alatako n lọ lọwọ ni oun gba ipe lati ile iṣẹ aarẹ.

O ni nibi ipade oun pẹlu ile iṣẹ aarẹ l'oun ti gba lati ṣiṣẹ pẹlu ẹgbẹ osẹlu APC nipinlẹ Oyo.

Akala Ladoja sọ fun oun nibi ipade naa pe oun ko le lanfani lati dije fun ipo gomina nitori oun kii ṣe ọmọ Ibadan.

O ni idi eleyi lo mu oun gba lati ṣiṣẹ pelẹ ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Oyo.