Olamiju Akala: Ẹgbẹ́ APC dá ọmọ Alao Akala padà sípò alága Ogbomọṣọ North

Alao Akala ati Ọlamiju

Oríṣun àwòrán, Adebayo Alao-Akala

Àkọlé àwòrán, Ọlamiju sọ pe 'wọn sọ pe awọn da oun pada lẹyin ti iwadi awọn fihan pe oun ko ṣẹ.'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti da Olamiju Akala pada si ipo rẹ gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ North.

Eyi waye lẹyin wakati diẹ ti baba rẹ, to jẹ oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, wọgile erongba rẹ, to si ni oun yoo ṣatilẹyin fun oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Adebayọ Adelabu.

Botilẹjẹ wi pe Ọlamiju sọ pe dida ti wọn da oun pada ko ni nkankan ṣe pẹlu igbesẹ ti baba oun gbe.

Ọlamiju sọ pe 'wọn sọ pe awọn da oun pada lẹyin ti iwadi awọn fihan pe oun ko ṣẹ.'

Àkọlé fídíò, Akala: Kọmísánà kò láṣẹ láti búra fún igbákejì mi bíi alága ìbílẹ̀

Ọjọ Abamẹta ni wọn da a pada si ipo rẹ gẹgẹ bi alaga, ti yoo si bẹrẹ iṣẹ pada lọjọ Aje, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta 2019.

Ọjọ diẹ lẹyin ti Ọlamiju ṣatilẹyin gbangba fun baba rẹ to n dupo gomina ni wọn yọ nipo, ti wọn si bura fun igbakeji rẹ gẹgẹ bi alaga tuntun.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

O ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba pe wọn yọ oun kuro nipo nitori pe oun kuro lẹgbẹ APC lọ ọ darapọ mọ ẹgbẹ ADP lati ṣatilẹyin fun baba oun.

O si leri lati gbe ijọba ipinlẹ Ọyọ lọ sile ẹjọ.