Ìpàdé ẹgbẹ́ alátakò: Makinde,Lanlehin kò tíì sọ ìgbésẹ̀ tí ọrọ kàn
Ipade laarin awọn ẹgbẹ oṣelu alatako niluu Ibadan lori bi wọn yoo ṣe darapọ jẹ ọkan lati koju ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo gomina ọsẹ to n bọ ko tii fẹnu ko sibi kan.
Ipade naa to waye ni Bodija nile gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri Rashidi Ladoja ti wa sopin fun ti ọjọ Ẹti ṣugbọn yoo tẹsiwaju lọjọ Abamẹta.

Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ ADP Adebayo Alao Akala ko ti sọ igbesẹ rẹ titi di asiko yii
Sẹnẹtọ Olufemi Lanlẹhin ti ẹgbẹ ADC pẹlu Seyi Makinde naa wa nibi ipade ọhun.
Oludije fẹgbẹ SDP Bolaji Ayorinde, Sharafedeen Alli ti ẹgbẹ ZLP naa wa nibi ipade naa.

Akala ti kọkọ ṣepade pẹlu eekan ninu ẹgbẹ APC Bola Tinubu l'Ọjọru lori idibo gomina osẹ to n bọ yii naa.









