Governorship Election Results: Àwọn àwòrán ìdùnnú rèé lẹ́yìn ìkéde èsì ìbò

Ọjọ Satide ni eto idibo gomina ati tile asofin ipinlẹ waye nilẹ Naijiria, ti ajọ INEC si ti kede esi ibo lawn ipinlẹ kan.

Babajide Sanwo-Olu n gba ipe
Àkọlé àwòrán, Babajide Sanwo-Olu, to sẹsẹ bori ibo gomina nipinlẹ Eko ree, to n gba ipe ku oriire latọdọ alatako rẹ, Jimi Agbaje
Awọn eeyan to n sajọyọ nile Dapọ Abiọdun
Àkọlé àwòrán, Amala da, abula nkọ? Ẹ fun wa lomi tutu. Ariwo yii lo gba ilẹ kan nile Dapọ Abiọdun to bori ibo gomina nipinlẹ Ogun
Awọn eeyan to n sajọyọ nile Dapọ Abiọdun
Àkọlé àwòrán, Ẹsẹ giri nile oloriire lawn eeyan n se nile Dapọ Abiọdun nigba to bori ibo gomina nipinlẹ Ogun
Aafa to we nkan mọ ọrun
Àkọlé àwòrán, "Haa, eyi o wa pọ ju" lawọn eeyan n se nigba ti wọn ri ọrun Alfa yii
Abdulrahman Abdulrazaq
Àkọlé àwòrán, Ẹrin lẹnu mi, lẹyin ta dibo tan. Orin yii ni Abdulrahman Abdulrazaq mu bọ ẹnu ni kete ti INEC kede pe oun lo di gomina tuntun nipinlẹ Kwara
Ero nile Dapo Abiodun
Àkọlé àwòrán, Emi yoo ba oloriire yọ nitemi. Ọgọọrọ ero lo pe sile Dapọ ASbiọdun to moke ninu ibo gomina nipinlẹ Ogun
Awọn eeyan to n sajọyọ nile Dapọ Abiọdun
Àkọlé àwòrán, Oluwa seun ooooo, Awọn eeyan fo soke nigba ti wọn gbọ pe Abdulrazaq Abdulrahman lo bori ibo gomina nipinlẹ Kwara
Dapo Abiọdun ati Babajide Sanwo-Olu
Àkọlé àwòrán, Awa oloriire ree o. Dapọ Abiọdun ree ati Babajide Sanwo-Olu, ti wọn sẹsẹ jawe olubori nipinlẹ Ogun ati Eko
Awọn eeyan to n sajọyọ nile Dapọ Abiọdun
Àkọlé àwòrán, Haa! Faaji lo n san yii nile Dapọ Abiọdun, lẹyin ti INEC kede pe o moke ninu ibo gomina nipinlẹ Ogun
Awọn eeyan to n sajọyọ nile Dapọ Abiọdun
Àkọlé àwòrán, Ariya ti bẹrẹ nile Dapọ Abiọdun
Iyawo Sanwo-Olu dọbalẹ gbalaja lati yin Ọlọrun logo

Oríṣun àwòrán, jokesanwoolu

Àkọlé àwòrán, "Oluwa, ẹyin lẹ seyi fun wa, a dupẹ ooo". Iyawo Babajide Sanwo-Olu n yika lori idọbalẹ fun Oluwa lẹyin ti ọkọ rẹ moke ninu ibo gomina
Seyi Makinde nawọ soke lati dupẹ pe oun wọle ibo
Àkọlé àwòrán, "Mo dupẹ pupọ pe mo wọle ibo", Seyi Makinde yin Ọlọrun logo