Darius Ishaku: Ìbò 520,432 ló ní, tí olùdíje APC sì ní ìbò 362,735

Darius Ishaku

Oríṣun àwòrán, @@dariusdishaku

Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu PDP, to tun jẹ gomina ipinlẹ Taraba, Darius Ishaku, ni ajọ eleto idibo ti kede pe o moke ninu ibo gomina ti wn di lọjọ Satide.

Ishaku lo ni ibo 520,432, to si moke ni ijọba ibilẹ mejila ninu ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ naa.

Alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu APC, to se ipo keji ninu ibo naa, Alhaji Sani Abubakar Danladi lo ni ibo 362,735, to si rọwọmu nijọba ibilẹ mẹrin pere.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Nigba to n kede esi ibo naa, ni olu ileesẹ ajọ Inec to wa nilu Jalingo, Ọjọgbọn Shehu Iya ni niwọn igba to j pe gomina Ishaku lo gba iye ibo to pọ julọ, oun lo bori ibo naa.