2019 elections: Fayoṣe ní kò sí ìyàtọ̀ láàárín Buhari àtàwọn ọ̀daràn bíi Shina Rambo, Evans ajọmọgbé

Oríṣun àwòrán, Ayodele Fayose
Gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ti ni ajọṣepọ kan n bẹ laaarin aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari atawọn gbajugbaja ọdaran lorilẹede Naijiria bii Anini, Oyenusi ati Evans ajọmọgbe.
Gbogbo eeyan lo mọ awọn ọdaran wọnyii ati iwa laabi wọn lawujọ, ṣugbsn ohun to ṣokunkun naa ni ibi ti aarẹ Buhari ti wa fara jọ wọn o.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọṣa, Fayoṣe ṣalaye lori oju opo twitter rẹ pe bi a ba n sọrọ ṣiṣe eto idibo ti ko ni makaruru ninu, eleyi to ni aarẹ n tẹnu mọ lẹnu ọjọ mẹta yii, bi igba ti eeyan ba ni ki awsn gbajugbaja ọdaran wọnyii o maa ṣe ileri awujọ ti ko ni iwa ọdaran ninu ni.
Fayoṣe ni ileri ti aarẹ Buhari n ṣe lati ṣeto idibo alailabawọn ninu ko lee ṣeeṣe nitori bi igba ti eeyan n ni ki awọn ọdaran o maa o maa ṣe ileri ati fi ohun ti wọn fi n ṣe fuja lawujọ silẹ ni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ninu awọn ọrọ to fi si oju opo twitter rẹ ọhun, Fayoṣe tun bu ẹnu atẹ lu bi aarẹ ṣe kuna lati buwọ lu iwe abadofin idibo tuntun eleyii to ni o kan lilo ẹrọ ayẹkaadi idibo wo ni dandan lasiko idibo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ninu awọn atẹjade oju opo twitter rẹ ọhun, Fayose ni: "Buhari n sọ pe afojusun oun ni lati fi ogun eto idibo alailabawọn lelẹ, ileri yii dabi igba ti Oyenusi, Shina rambo, Anini ati Evans ajọmọgbe ba n leri ati fi ogun awujọ ti ko ni iwa ọdaran lelẹ fun Naijiria."








