BREXIT: Geoffrey Cox ni àwọn ìdíwọ́ tó leè de ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì mọ́lẹ̀ kò tíì yí padà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amofin agba ilẹ Gẹẹsi ti sọ pe bi ọrọ ti ṣe n lọ yii, afaimọ ki ilẹ Gẹẹsi o maa ṣi wa labẹ ofin ajọ ilẹ Yuroopu, lẹyin ti wọn ba fi ajọ naa silẹ pẹlupẹlu awọn ayipada ti olootu ijọba ilẹ naa ti ṣe si eto naa.
Geoffery Cox ni ko si ọna abayọ miran lati yanju iṣoro orilẹede Ireland lori igbesẹ ati fi ajọ naa silẹ lai si pe ajọ EU paapaa jẹ hoo sii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni igba ti olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May gbe adehun yiys ilẹ Gẹẹsi kuro ni ajs naa ka iwaju awọn aṣofin ni oṣu kinni nṣe lawọn aṣofin bu omi paa.
Amọṣa, iwoye awọn amoye kan ni pe yoo fẹ nira fun olootu May lati yi oju ọrọ naa pada ti a ba wo iye awọn eeyan to tako o ni igba akọkọ.
Kini wọn fẹnuko le?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May rinrinajolọ si igbimọ aṣofin ajọ orilẹede Yuroopu, EU pẹlu akọwe eto atikuro lajọ ọhun, iyẹn Brexit, Ọgbẹni Steve Barclay fun ipade pataki pẹlu Ọgbẹni Juncker ati Michel Barnier to jẹ alarinna lori eto naa, adehun waye lori awọn iwe kan.
"Iwe adehun to de awọn igun tọrọ kan" lori bi ilẹ Gẹẹsi ṣe fẹ kuro eleyi ti wọn lee lo lati bẹrẹ igbesẹ ẹhonu bi ajọ EU ba fẹ de ilẹ Gẹẹsi mọlẹ tipatipa.
Iwe adehun lori ajọṣepọ laaarin ilẹ Gẹẹsi ati ajọ EU lọjọ iwaju eyi ti yoo wa ilana miran dipo gbogbo ọna lati de ajọ naa mọlẹ loṣu kejila ọdun 2020.
Agbekalẹ aladaṣe kan eyi to laa kalẹ pe ko si ohun kan to lee di ilẹ Gẹẹsi lọwọ bi ijiroro ba foriṣanpọn laaarin ilẹ Gẹẹsi ati ajọ ilẹ Yuroopu lọjọ iwaju.
Ọpọ awọn aṣofin lo n bẹru pe awọn igbesẹ kan eleyi ti ilẹ Gẹẹsi kọkọ ṣeto rẹ ni oṣu kejila ọdun 2017 lee di ilẹ Gẹẹọi lọwọ ki o si fẹ sọs di isọmọgbe ajọ EU.
Ikilọ ajọ EU

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilẹ Gẹẹsi yoo fi ajọ EU silẹ ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2019 lẹyin ti wọn ti dibo bẹni tabi bẹẹkọ laaarin awọn eeyan orilẹede naa. Ninu ibo ọhun ida mejilelaadọta ninu ọgọrun, 52%, lo sọ pe awọn faramọ ki ilẹ Gẹẹsi o kuro ni ajọ EU, ida mejidinlaadọta ninu ọgọrun 48% si ni rara awọn ko faramọ ọ. Eyi ti tums si pe, eeyan miliọnu mẹtadinlogun o le irinwo ẹgbẹrun lo dibo bẹẹni, ti eeyan miliọnu mẹrindinlogun o le ọgọrun ẹgbẹrun si dibo bẹẹkọ ni ọdun 2016.
Ọgbẹni Juncker ti kọkọ ṣekilọ fawọn aṣofin ilẹ Gẹẹsi pe ọrọ naa yoo lẹyin bi wọn ba tun dibo lati bu omi pa igbesẹ naa.
"Ninu eto oṣelu, awọn asiko kan maa n wa fun anfani ẹẹkeji, nnkan ti a ba wa fi anfani naa ṣe ku si wa lọwọ. Ko lee si anfani igba kẹta."













