APC: Akeredolu ti gba ‘Kueri’lórí aṣemáṣe rẹ̀ nínú ẹgbẹ́

Oríṣun àwòrán, Saharareporters
O ṣeeṣe ki ẹgbẹ oṣelu APC ni ki gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lọ rọkun nile fun igba diẹ, lẹyin to ba fesi lori iwe wa-wi-tẹnu-rẹ to gba, lati ọwọ igbimọ amuṣẹya (NWC) ẹgbẹ naa nitori pe o n gbe awọn igbesẹ to lodi si ifẹ ẹgbẹ oṣelu naa.
Agbẹnusọ fun APC, Lanre Issa-Onilu, sọ fun BBC Yoruba pe, Akeredolu ni gomina kẹta ti wọn yoo fun ni iwe wa salaye ara rẹ (Query) lori iru ẹsun yii. Awọn meji to ku ni Gomina Ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, ati Gomina Ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha.
Àwọn ìròyìn tí a lé nífẹ̀ẹ́ sí:
Issa-Onilu ṣalaye wipe, awọn igbesẹ kan pọn dandan ti wọn ba ti jawe wa-wi-tẹnu-rẹ fun ẹnikẹni ninu ẹgbẹ APC. O ni lẹyin awọn iwadii kọọkan ti wọn ba ṣe, ti o ba jẹ pe Akeredolu kuna ninu awọn ọna to pọ, wọn le ni ko lọ rọkun nile fun igba diẹ na.
Atẹjade kan lati ọdọ Akeredolu ti kọkọ sọ wipe, irọ ni wipe wọn ti kọwe wa-wi-tẹnu-rẹ si gomina naa, sugbọn awọn iroyin miiran tun fi han wipe, gomina Akeredolu n mura lati fi ẹgbẹ APC silẹ lọ AA.
Nigba ti a kan si agbẹnusọ rẹ, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale lati fidi rẹ mulẹ pe se lootọ ni Akeredolu n fi ẹgbẹ́ APC silẹ, o sọ ninu atẹjisẹ kan to fi dahun ibeere naa pe, "kii se ohun to le daindain pe Aketi n fi ẹgbẹ APC silẹ́."
Ọdẹbọwale ni, "O ti mọ wa lara lati maa koju ipenija, eyi to n sẹlẹ yii naa ko si yatọ. Emi ko ti i ri iwe kankan ti APC kọ si gomina. Ẹnikẹni to ba ni Aketi fẹ lọ ẹgbẹ oṣelu miiran ko mo oun to n sọ."









