Ìbẹ̀rù mú ọ̀pọ̀ èèyàn bí wọ́n ṣe rí epo dísù nínú kànga n'Ibadan èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbọ́n

Ẹnikan to duro laarin ọpọ ero, n fa epo disu lati inu kanga ni Yemetu n'Ibadan pẹlu dooro ifami awọ olomi ọsan

Oríṣun àwòrán, Olaide Oyewole

Àkọlé àwòrán, Kanga naa to wa laarin agboole kan ni Yemetu lo ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ bayii lori itakun ayelujara.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ kan to waye ladugbo Yemetu nilu Ibadan nibi ti epo Disu ti n sun jade lati inu kanga.

Se ni ariwo gba ori ayelujara kan, ti ọpọ eeyan si n kọminu nipa ijamba ti isẹlẹ naa le mu ba awọn eeyan agbegbe naa.

Fidio kan to ti lu ori itakun ayelujara pa bayii, lo ṣafihan bi ọpọ olugbe ilu Ibadan, ṣe n ya lọ sibi kanga naa lati gbọn epo disu.

Kanga naa to wa laarin agboole kan ni Yemetu lo ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ bayii lori itakun ayelujara.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti wa sọrọ lori isẹlẹ naa ati idi ti wọn se ri epo disu ninu kanga naa.

Ọkunrin kan gbe epo disu to rọ sinu ike lọwọ lẹgbẹ kanga ti wọn ri epo ninu rẹ n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Olaide Oyewole

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ni irọlẹ ọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja lawọn eeyan kan fi to awọn leti pe awọn ri epo ninu kanga kan lagbegbe Omikunle ni Yemetu.

''O ṣee ṣe ko jẹ pe inu tanki ti wọn ri mọlẹ ni epo disu naa ti n jo lọ sinu kangan''

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ni irọlẹ ọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja lawọn eeyan kan fi to awọn leti pe awọn ri epo ninu kanga kan lagbegbe Omikunle ni Yemetu.

Bayii ni ọga ọlọpaa DPO agbegbe naa moju lọ sibẹ pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ lati ṣe iwadii ohun to ṣẹlẹ gan an.

Nigba tawọn ọlọpaa de ibẹ ni wọn fidi rẹ mulẹ pe epo disu lo wa ninu kanga ọhun..

Kete tawọn ọlọpaa de ibẹ ni wọn ri pe ọpọ eeyan ladugbo naa ni wọn ti ko oriṣiiriṣii jẹrika atawọn nnkan mii ti wọn fi le gbọn epo.

Eyi lo jẹ ki awọn ọlọpaa duro sibẹ kawọn eeyan ma le lanfaani lati maa gbọn epo naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn tun ti kepe ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika lati ṣe iranwọ ati gbọn epo naa kuro ninu kanga ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ pe iwadii awọn fi han pe o ṣee ṣe ko jẹ pe lati inu tanki kan ti wọn ri mọlẹ ni epo disu naa ti n jo lọ sinu kangan ọhun.

Amọ, ni bayii, ko si ibẹru-bojo lagbegbe naa mọ, nigba ti iwadii ọlọpaa si n tẹsiwaju.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn araalu lati maa gbiyanju sọ fun ọlọpaa ti wọn kẹfin nnkan to ṣajeji.

Epo disu ninu kanga ni Yemetu n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Olaide Oyewole

Àkọlé àwòrán, Kete tawọn ọlọpaa de ibẹ ni wọn ri pe ọpọ eeyan ladugbo naa ni wọn ti ko oriṣiiriṣii jẹrika atawọn nnkan mii ti wọn fi le gbọn epo.

Ki ni awọn ara adugbo Yemetu sọ lori epo disu ti wọn ri ninu kanga?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn olugbe adugbo naa ko tiẹ kọkọ mọ pe epo disu lo wa ninu kanga ọhun, ki iwadii ileeṣẹ ọlọpaa to fidi rẹ mulẹ pe disu ni.

Awọn eeyan kan lagbegbe Omikunle ṣalaye pe awọn ti n pọn omi ninu kanga naa ṣaaju akoko yii ti ko si si nnkan to jọ epo nibẹ.

Bukola Olakunle to jẹ ọkan lara awọn to n gbe ile ti kanga naa wa ṣalaye pe nigba toun n pọn omi ninu kanga ọhun lọjọ Satide to kọja loun ṣakiyesi pe epo disu ti kun inu kanga naa.

''Dipo ki n ri omi to mọ gaara pọn, epo disu ni dooro ifami pọn jade lati inu kanga.

Bayii ni mo ke gbajare ti mo si pe akiyesi gbogbo ara adugbo si nnkan ti mo ri.

Lẹyin naa lawọn ẹsọ eleto abo de, ti wọn si ti gbe kanga naa tipa,'' Olakunle ṣalaye.

Ẹlomiran toun naa n gbe lagbegbe ọhun, Fatima Gafar, ni iyalẹnu nla lo jẹ foun bi awọn ṣe ri epo disu ninu kanga tawọn ti maa n pọn omi.

Gafar naa sọ pe o sẹe ṣe ko jẹ wi pe lati inu tanki ile epo kan ti wọn ri mọlẹ ni epo disu naa ti n jo lọ sinu kanga.

Nnkan mii tawọn kan tun n fura si ni opo ''mast'' ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ to wa lẹgbẹ ile ti kanga ọhun wa.

Awọn kan sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ wi pe lati ibẹ ni epo naa ti n jo lọ sinu kanga.