"Òpó iná IKEDC ló wó lù mí lọ́dún méje sẹ́yìn, ń kò le rìn tàbí dá jẹun, ọ̀rá ni mo fi ń tọ̀, owó ti tán, mo ná N3m láti wo egbò ara mi"

Àkọlé fídíò, "Òpó iná IKEDC ló wó lù mí lọ́dún méje sẹ́yìn, ń kò le rìn tàbí dá jẹun, ọ̀rá ni mofi ń tọ̀, mo ná N3m láti wo egbò ara mi"
"Òpó iná IKEDC ló wó lù mí lọ́dún méje sẹ́yìn, ń kò le rìn tàbí dá jẹun, ọ̀rá ni mo fi ń tọ̀, owó ti tán, mo ná N3m láti wo egbò ara mi"

Yoruba maa n gbadura pe ki Ọba Oke mase jẹ ka rin ni ọjọ ti ebi yoo ba ọna.

Bakan naa ni wọn maa n gbadura pe ka mase rin arinfẹsẹsi, ka mase se kongẹ ibi.

Amọ obinrin kan ree to se agbako isẹlẹ nla kan lasiko to n ti ibi isẹ bọ eyi to sọ di alaabọ ara.

Obinrin naa, Onilude Muibat, ni ko le rin tabi da dide nilẹ, to si jẹ pe kẹkẹ lo fi n gbera.

BBC News Yoruba de ile obinrin naa lati mọ ohun to gbe de ipo yii, alaye rẹ si mu omi loju ẹni.

A si n sekilọ pe awọn aworan to ka ni laya wa ninu fidio oke yii, ẹ mu ọkan le lasiko ti ẹ ba n wo o.

Muibat Onilude joko si ori kẹkẹ awọn alaabọ ara, o wọ asọ buba pupa ati sokoto penpe. O di iru adisẹyin, o si fi ọwọ osi le ẹrẹkẹ rẹ.
Àkọlé àwòrán, Muibat Onilude

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Muibat Onilude salaye pe isẹlẹ to waye, ti oun fi di alaabọ ara ojiji, kii se amuwa Ọlọrun rara.

O ni opo ina kan to ku diẹ ko wo lo fa sababi, ti wn si n ke si ajọ amunawa pe ki wọn wa yọ opo naa, amọ ti wọn ko wa yọ.

"Ọdọ ileesẹ to n pese ina ọba to wa ni adugbo Ikeja, Ikeja Electricity Distribution Company (IKEDC) lo ni ẹbi bi isẹlẹ naa se waye.

Ogunjọ Osu Keje ọdun 2018 ni opo ina wo lu mi lori lasiko ti mo n ti ibi isẹ bọ.

Opo ina naa ti n fẹ da wo, tawọn eeyan si ti n ke si wọn lati wa yọ opo naa amọ ti wn ko wa yọ ọ.

Mo ranti pe mo pọn ọmọ sẹyin lọjọ naa amọ nigba to ya, n ko mọ ohunkohun mọ, lẹyin osu diẹ ni mo to yaju nile iwosan.

Wọn sọ fun mi pe opo ina wo lu mi pẹlu ọmọ lẹyin, ti mo si wo sinu gọta, opo ina naa si wa lori mi."

Obinrin kan to wọ asọ alawọ elese aluko ati ọkunrin kan to wọ ankara alawọ elewo duro ni apa osi ati ọtun Muibat Onilude. Obinrin naa gbe ẹsẹ Muibat Onilude nigba ti ọkunrin gbe ori rẹ soke lati gbe kuro lori ibusun ti wọn tẹ si.
Àkọlé àwòrán, Wọn n gbe Muibat Onilude kuro lori ibunsun.

"N ko le da tọ funra mi, ọra ni wọn so mọ mi lara lati tọ, wọn si maa n de idi fun mi bii ọmọde"

Muibat Onilude wa n da omi loju poroporo pe isẹlẹ naa ti ba aye oun jẹ, ti oun si n rawọ ẹbẹ si ajọ IKEDC lati ran oun lọwọ.

"N ko le da tọ funra mi, ọra ni wọn so mọ mi lara lati tọ, wọn si maa n de idi fun mi bii ọmọde.

Koda, n ko le da jẹun funra mi, wọn maa n nu mi ni ounjẹ ni, n ko le da se nkankan, oore ọfẹ Ọlọrun ni mo fi n mi.

A ti ta ilẹ, a ti ta ile, a ti ya owo, a jẹ awọn to n na egungun fun mi lowo, ni a se ni ki wn da ọwọ isẹ wọn duro.

Owo n lọ lojoojumọ, egbo lo wa ni gbogbo ara mi, o le ni milliọnu mẹta Naira ti a lọ fi wo ọpọ egbo to wa ni ara mi nile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti ni Eko, LUTH."

Muibat Onilude joko si ori ibusun, o wọ asọ buba pupa, o si da ankara alawọ dudu, yẹlo ati pọpu bo ẹsẹ. O di iru adisẹyin, o si gbe ọwọ osi rẹ sori timutimu kan.

"Aini akasi ileesẹ IKDEC lo mu mi de ipo ti mo wa yii, ki wọn jọọ, saanu mi, ran mi lọwọ"

Nigba to n salaye igbesẹ to ti gbe lati kan si ajọ IKEDC, Muibat Onilude salaye pe awọn ti kọ iwe si ileesẹ amunawa naa ni igba meji amọ wọn ko dahun.

"Mo n bẹ olori ileesẹ IKEDC naa pe ki wọ̀n tori Ọlọrun saanu fun mi, tori n ko ni ireti kankan mọ.

Aini akasi wọn lo mu mi de ipo ti mo wa yii, ki wọn jọọ, saanu mi.

Dokita gan ni ki a lọ ya opo ina to wo lu mi naa amọ nigba ti a de ibẹ, a ko ri opo naa mọ."

BBC News Yoruba wa kan si ileesẹ amunawa IKEDC lati gbọ ti ẹnu wọn amọ gbogbo aayan wa lo ja si pabo.