Bàtà mi ẹsẹ̀ kan làwọn ìkà lò láti mú kí ẹsẹ̀ mi méjèèjì rọ - Grace Garuba

Àkọlé fídíò, Disabled Shoemaker: Grace Garuba ní ọwọ́ àti orúnkún ní òun fi ń fà láti pa èkùrọ́ jẹun
Bàtà mi ẹsẹ̀ kan làwọn ìkà lò láti mú kí ẹsẹ̀ mi méjèèjì rọ - Grace Garuba

Yoruba ni ba ti waye pe a ri, naa la maa n ri, ko si si ohun ti ẹda le se lẹyin ori ati akunlẹyan rẹ to ba dele aye ba.

Arẹwa obinrin ni Garuba Shehu, ti awọn obi rẹ si bi sile aye pẹlu gbogbo ẹya ara rẹ to pe, gẹgẹ bi ọmọ tuntun se maa n pe.

Amọ lasiko ti BBC Yoruba se alabapade rẹ, se lo n fi igi rin, to si ni sọọbu kan to ti n se atunse bata lai naani ipenija ara rẹ.

Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ ọ lọ lati mọ ohun to sun de ipo yii gẹgẹ bii obinrin agbalagba ati awọn ipenija to n doju kọ ọ.

Grace Garuba

“Bata mi ẹsẹ kan ni wọn mu lati sisẹ bi, to fi jẹ ki n rọ lẹsẹ mejeeji”

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Grace Garuba ni oun n dagba titi to fi pe ọmọ ọdun mẹwa, ki ajalu nla to de ba oun.

O ni ajalu naa si lo sọ oun di alaabọ ara lọsan gangan.

“Gẹgẹ bi iya mi ti salaye fun mi, mo sun lalẹ ọjọ kan ni, nigba ti mo pe ọmọ ọdun mẹwa.

Mo wa ji dide loru lati lọ tọ amọ n ko le gbe ẹsẹ mejeeji mọ, ti mo si figbe ta, bi ẹsẹ mi mejeeji se rọ lojiji niyẹn.

Mama mi ni oun sare kaakiri lati ri pe mo pada bọ sipo amọ wọn sọ fun pe bata mi ẹsẹ kan ni awọn arogo saaju ologo lo lati fi sisẹ ibi fun mi.”

Grace Garuba

“Osu kan ti iya mi ku, naa ni baba mi jade laye”

Nitẹsiwaju ọrọ rẹ, Grace Garuba salaye pe igbe aye ko dẹrun fun oun rara lori isẹlẹ yii.

Kaka ki ewe agbọn oun si dẹ lori igbe aye to le fun oun, ko ko ko lo tun n le si.

Idi ni pe o sọ pe ko pẹ lasiko ti isẹlẹ yii sẹ, ni iya oun jẹ ipe Ọlọrun.

O fikun pe lẹyin osu kan pere ti iya oun tẹri gbasọ naa ni baba oun tun jade laye.

Lati igba naa ni Grace ni oun ti n da bukata oun gbe lai si oluranlọwọ.

Grace Garuba

“Ọwọ ati orunkun ni mo n da delẹ, maa fa bii ọmọde lati pa ekurọ labule”

Grace Garuba salaye pe lẹyin iku awọn obi oun, atijẹun di ọran, ti ko si wu oun lati maa se agbe jẹun.

O ni idi ree ti oun fi n lọ ba awn eeyan to n pa ekurọ ta ni abule awọn lati maa pa ekurọ gba owo.

“Ọwọ ati orunkun ni mo n da delẹ, maa fa bii ọmọde lati pa ekurọ labule.

Ko wu mi ki n maa se agbe jẹun, ni mo se n sisẹ yii, ti mo si n ri tọrọ-kọbọ jẹun.”

Nigba to n salaye bo se bẹrẹ isẹ bata sise, Grace sọ pe oun dara pọ mọ ile ijọsin kan lati maa jọsin.

O ni ọpẹlọpẹ adura lo wo oun san de ibi ti oun wa yii, ti oun si le dide lati maa lo igi fi rin, ti oun ko si da ọwọ ati orunkun delẹ maa fa kiri mọ.

“Pasitọ ijọ ti mo n lọ lo ran mi lọwọ pe ki n lọ kọ isẹ baba sise.

Lẹyin ti mo gba ominira tan, wọn gba sọọbu fun mi ti mo si n se isẹ yii.”

“Ọpọ ipenija ni mo n koju, koda, ogun iya ọkọ lo le mi kuro nile ọkọ”

Grace Garuba wa mẹnuba awọn ipenija to n koju rẹ nile aye funBBC Yoruba.

“Awọn ọlọkada kii fẹ gbe mi gẹgẹ bii ero, ti maa si duro kalẹ lai ri ẹni ti yoo gbe mi.

Nigba miran ti ọkada ba si gbe mi, se ni mo maa n ja bọ kiri lori ọkada, Ọlọrun gan lo mọ idi ti ọkada ko fi tii se mi lese.

Koda, mo tun ni ipenija pẹlu awọn ọkunrin, wn ko setan lati fẹ mi tori n ko ni owo lọwọ.

Mo ti lọ sile ọkọ ri nigba kan amọ ogun iya ọkọ lo sọ mi di ẹni to n pada maa da gbe.”

Grace Garuba wa rọ awọn akanda ẹda bii tirẹ lati dẹkun ki wọn maa se agbe loju popo tabi maa wo ọwọ ọlọwọ, ki wọn to le jẹun.