Wo arábìnrin tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mọ́ín-mọ́ín pẹ̀lú N500, ti ó sì rán ọmọ ní fásítì, ra ọkọ̀, kọ́’lé níbẹ̀ lónìí
Yoruba bọ, wọn ori lo mọ iṣẹ aṣela laye, bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu arabinrin Stella Abosede Ayemowa ti o bẹrẹ iṣẹ mọin-mọin tita ṣugbọn ti o ti ṣoriire nibẹ lonii.
Arabinrin Ayemowa ni ''iya lo sun mi de idi mọi-mọi, mo bẹrẹ si ni se mọi-mọi niluu Ibadan pẹ̀lú ẹẹdẹgbẹta naira ni bii ọdun mẹtalelogun sẹyin bayii.
Owo kekere ni mo fi bẹrẹ mọin-mọin ṣise, ṣugbọn lonii, o ti di nla.
Mo ti fi tọ ọmọ lọ sile ẹkọ, mo ti fi ṣe nkan to daa, mo fi ra mọto, mo fi kọle, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun.
Iṣẹ mói-mọi yii ni mo fi tọ gbogbo awọn ọmọ mi nile ẹkọ to de ile ẹkọ fasiti.
Awọn ibeji ti wọn fi n pe mi lonii, ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Kwara ti wọn n pe ni KWASU ni wọn wa ni ipele kẹta bayii.''
Agbegbe SUBEB niluu Ilorin nipinlẹ Kwara ni arabinrin Ayemowa ti gbogbo eeyan mọ si iya ibeji onimọin-mọin ti n ṣiṣẹ rẹ.
''Lootọọ mo lọ ile ẹkọ ti a ti kọ nipa ase ati amojuto ile itura niluu Ibadan, amọ Ọlọrun kan sọ pe iṣẹ mọi-mọi yii ni mo fẹ yan laayo ni.
Oriṣiriiṣi mọi-mọi ni a ni nibi, bi a ṣe ni ẹlẹyin ni a ni ẹlẹdọ, ni a ni ẹlẹja, bẹẹ ni a ni mọi-mọi elede.
Koda akẹkọọgboye imọ olukọ NCE gan an wa lara awọn to ti wa kọṣẹ lọdọ mi ti wọn dẹ n ṣe daadaa.
Ọlọrun si fi iṣẹ yii kẹ wa, ki aago mẹwaa to lu, a ti maa n ta gbogbo ọja wa tan.
Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun gbogbo ohun to ṣe fun mi nidi iṣẹ mọin-mọin yii,'' arabinrin Ayemowa ṣalaye.






