Àwẹ̀ ni a nílò kìí ṣe Ìyanṣẹ́lódì - Oluwo

Aworan Ọba Akanbi

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Telu I

Oluwo ti Ile Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi ti rọ àwọn ọmọ Naijiria lati bẹrẹ awẹ gbígba nitori o jẹ nnkan pataki ti a nilo bayii dipo iyanṣẹlodi ti ko le ṣe anfani kankan.

Nínu atẹjade ti Ọba Akanbi buwọlu fun awọn akọroyin ni bi nnkan ṣe n lọ lorilẹede Naijiria ku diẹ kato lọwọ yii sugbọn oun ni igbagbọ ninu eto isejọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati yi nnkan pada.

O wa rọ gbogbo àwọn ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria lati gba ijiroro laye laarin awọn ati Ìjọba apapọ ati pe o se koko pe ki wọn fi ero awọn ọmọ Naijiria sokan ninu awọn igbesẹ wọn.

"Emi naa n jẹ ìrora. Gbogbo ni a jere ijọba yii. A ti ṣe ileri lati sin orilẹede tọkantọkan, asiko naa ree.

"O yẹ ki a kede awẹ kaakiri orilẹede Naijiria lati fi gbe ogun ti bi nnkan ṣe n lọ gẹgẹ bii awọn kan ṣe kede iyanṣẹlodi.

"Eto ọrọ aje to mẹyẹ naa kọgun sì ọdọ mi sugbọn mo ni ireti itan orilẹede Naijiria yoo yí pada si daada.

"Aarẹ Tinubu yoo se ohun to tọ ati eyi to yẹ. Tinubu ni Ọlọrun ran si wa, oun ni olugbala wa.

"Mo n wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria lati ṣe suuru fun Aarẹ Tinubu."