Àbájáde ìpàdé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lórí ìfẹ̀hónúhàn àwọn awakọ̀ rèé

Aworan ipade ọlọpaa pẹlu awọn awakọ

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣepade pẹlu awọn tọrọ kan gbọngbọn lẹka igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko lori ifẹhonuhan tawọn awakọ kan pinnu lati ṣe nipinlẹ naa laarọ ọjọ Aje.

Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinle Eko fi sita sọ pe awọn adari ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, aṣoju ijọba ipinlẹ Eko, aṣoju ajọ ẹṣọ oju popo ijọba ipinlẹ Eko (LASTMA) ati awọn adari ẹgbẹ awọn awakọ ero (NURTW) gbogbo lo peju sibi ipade ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin ṣalaye pe gbogbo ẹdun ọkan awọn awakọ naa ni wọn gbeyẹwo finni-finni.

“Gbogbo awọn alẹnulọrọ to peju sibi ipade naa fẹnu ko pe wọn ni lati ṣiṣẹ pọ lati mu ki awọn awakọ o tẹle gbogbo ofin irinna ki awọn agbofinro naa o si so ewe agbejẹ mọwọ.”

O ni awọn ẹgbẹ NURTW pinnu lati pe ipade gbogboogbo laarọ ọjọ aje lati yanju ọrọ naa.

Hundeyin fi kun un pe “ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fi da gbogbo araalu loju pe eto gbogbo ti to lati ri pe abo to peye wa fun wọn, ki wọn si maa iṣẹ oojọ wọn lọ lai si ifoya idunkoko mọni tabi ikonilayajẹ latọwọ ẹnikẹni”.

Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni igbakeji kọmiṣọna ajọ ọlọpaa to n moju to SCID, Waheed Ayilara, ati awọn akẹgbẹẹ rẹ lẹka iṣeto ati ti iṣakoso, Fatai Tijani ati Khan Saliu, to fi mọ CSP Yinka Egbeyemi ati CSP Shola Jejeloye.

Olubadamọran pataki fun gomina Eko lori eto irinna, Sola Giwa, ati ọga agba ajọ LASTMA, Bolaji Oreagba, naa wa ni bẹ, ti Sulyman Ojora (Kudeti) si dari awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ nibi ipade ọhun.