Àwọn òṣìṣẹ́ OAUTH gbéná wojú àwọn aláṣẹ nítorí gbèsè owó oṣù mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, @TheGreatestIFE
Awọn kan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Obafemi Awolowo to wa niluu Ile Ife, OAUTH, ti gbena woju awọn alaṣẹ fasiti naa bayii latari pe wọn o san owo oṣu wọn fun oṣu mẹwaa gbako.
Ileeṣẹ iroyin abẹle Punch jabọ pe awọn oṣiṣẹ naa ni awọn ti di atọrọ jẹ bayii lọna ati bọ awọn mọlẹbi wọn.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ naa to pe ara rẹ ni Ben, ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin naa pe oun ko tii gba owo oṣu kankan lati inu oṣu Kejila ọdun to kọja ti oun ti darapọ mọ ile iwosan naa.
Ben sọ pe “Wọn fun mi ni iwe igbanisiṣẹ lọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun 2022 lẹyin ti mo pari ayẹwo ilera to yẹ ki n ṣe.”
“Lati igba naa wa ni iya pọnbele t n jẹ mi; wọn ko san owo oṣu kankan fun mi gẹgẹ bii oṣiṣẹ.”
“Mo ti lọ gba ile pẹlu owo ti mo ni ipamọ tẹlẹ, mo tun ṣe ọpọ nnkan mii sibẹ ni ireti pe wọn maa fun mi owo oṣu ti mo ti maa yọ owo naa pada amọ mi o ri nnkankan.”
Oṣiṣẹ mii to tun sọrọ amọ ti ko fẹ fi orukẹ rẹ lede sọ pe owo oṣu ti wọn n jẹ oṣiṣẹ ati bi ko ṣe tọju awọn oṣiṣẹ eto ilera daadaa lo jẹ ki ọpọ ninu wọn maa japa lọ silẹ mii.
O ni “Bawo ni odidi oṣiṣẹ eto ilera yoo ṣe maa ṣiṣẹ nile ẹkọṣẹ iṣegun ijọba apapọ fun oṣu mẹwaa gbako ti ko ni gba kọbọ kan latari pe a ko tii si ninu ẹrọ IPPIS nitori idi kan tabi omiran to ye awọn alaṣẹ.”
“Ọpọ eeyan lo ti di idakuda, ọpọ oṣiṣẹ lo ti wọ oko gbese lọ, idile awọn mii ti n tuka, ti ọpọ ko si le san owo ile ẹkọ awọn ọmọ wọn, bawo ni ẹ ṣe fẹ ki ọkan irufẹ eeyan bẹẹ balẹ?”
Ọkunrin naa ṣalaye siwaju si pe gbogbo ẹbẹ awọn lo n bọ si eti ikun awọn alaṣẹ ile iwosan naa, koda awọn ẹgbẹ kan bii JOESU ti fi akoko igba kan gunle iyanṣẹlodi lori ọrọ naa amọ pabo ni gbogbo akitiyan wọn ja si.
Lẹyin naa lo ke si awọn ọmọ Naijiria atawọn alaṣẹ OAUTH ki wọn ṣaanu awọn nitori iya to n jẹ awọn ko ṣe e farada mọ.
A ti bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ naa - Minisita
Ẹwẹ, nigba ti awọn akọroyin kan si adari OAUTH, John Okeniyi, o ni oun ko lanfani lati sọ ohunk ohun lori ọrọ naa lakoko yii.
O ni “Mi o tii le sọrọ kankan nipa rẹ bayii nitori minisita eto ilera ti da si ọrọ naa ṣaaju, mo ṣi n reti itọni lati ọdọ rẹ.”
Ṣaaju ni minisita naa ti sọ loju opo X rẹ pe oun mọ nipa inira ti awọn oṣiṣẹ naa n dojukọ ni OAUTH, ṣugbọn iṣẹ ti n lọ lọwọ lati yanju rẹ.












