Àwọn adigunjalè yọ ìbọn sí Mínístà, wọ́n lu àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ lálùbami

SINDISIWE

Oríṣun àwòrán, @Google

Iyalẹnu nla ni iṣẹlẹ idigunjale to ṣẹlẹ si minista fun fun eto igbokegbodo ọkọ, Sindisiwe Chikunga, ṣi n jẹ, pẹlu bawọn adigunjale ṣe da mọto rẹ duro, ti wọn gbe ibọn si i lori lọjọ Aje ọṣẹ yii loju ọna nla Johannesburg, lorilẹ-ede South Afrika, ti wọn si gbe awọn ẹrọ alagbeeletan ati foonu rẹ lọ.

Abilekọ Chikunga ṣalaye nipa bi iṣẹlẹ yii ṣe ko o laya soke to si jẹ nnkan iyanu. Minista naa sọ pe ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ Mọnde ọsẹ yii ni awọn adigunjale da mọto oun duro, lasiko ti taya ọkọ naa bẹ toun si duro pẹlu awọn ẹṣọ oun lati tun un ṣe.

O ni o ya oun lẹnu bi wọn ṣe lu awọn ẹṣọ naa bole, ti wọn ko bẹru wọn rara, ti wọn si gbe ibọn siwaju ori oun, ti wọn n beere owo .

‘’ Mi o lowo ninu ọkọ, bi wọn ṣe bẹrẹ si i da gbogbo inu mọto mi ru niyẹn ti wọn ko awọn kọmputa alagbeeletan ati foonu lọ’’ Bẹẹ ni minista ṣalaye.

O tilẹ sọ pe awọn adigunjale naa tun fẹẹ gba oruka igbeyawo oun pẹlu, o niṣe loun bẹ wọn pe ohun kan ṣosọ to so oun ati ọkọ oun to di oloogbe pọ niyi, ki wọn jọwọ ma gba a lọwọ oun.

O ni nigba toun n gbadura lasiko ti wọn gbebọn soun lori naa, awọn ole naa paṣẹ pe koun dakẹ ẹnu oun kia, loun ba yaa dakẹ jẹẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa South Afrika ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, bẹẹ lawọn n wa awọn to kọlu iya naa.