Ìdìbò Gómìnà Imo, tá ní yóò já mọ lọ́wọ́ láàrin àwọn Sẹ́nétọ̀ ẹgbẹ́ PDP tẹ́lẹ̀ tó n kópa

Oríṣun àwòrán, UZIDIMMA/ACHONU/ANYANWU/FACEBOOK
Ti ko ba si idiwọ kankan,idibo Gomina ipinlẹ Imo yoo waye lopin ọsẹ yi lati mọ boya Gomina Hope Uzodinma to wa lori alefa naa ni yoo tẹsiwaju tabi ẹlomiran yoo di Gomina ipinlẹ ọhun.
Ninu awọn to n du ipo yi la ri Sẹnẹtọ mẹta tẹlẹ ri ti wọn fẹ di Gomina ipinlẹ naa.
Hope Uzodinma to jẹ Gomina bayii ti ṣe Sẹnẹtọ ri pẹlu awọn meji mii ti wọn ṣju ẹkun idibo meji to ku ni ipinlẹ Imo.
Awọn wọnyii ni Sẹnatọ Samuel Anyanwu ti ẹgbẹ Peoples Democratic Party ati Sẹnatọ Athan Achonu ti ẹgbẹ Labour Party.
Awọn mẹtẹẹta yi ti fi igba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ki wọn to ya lọ si ẹgbẹ mii lonii.
Laarin awọn mẹtẹẹta yi ni ipo naa yoo ja mọ ẹni kan lọwọ ninu wọn.
Diẹ ree ninu awọn nkan to yẹ ko mọ nipa wọn ṣaaju ọjọ idibo lopin ọsẹ to wọle de yi.
Hope Uzodinma ẹgbẹ APC

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/UZODIMMA
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress.
Sẹnẹtọ Hope Uzodinma ni alaga ẹgbẹ awọn Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
Saaju ko to di Gomina labẹ APC o dipo sẹnẹtọ mu labẹ aisa ẹgbẹ Peoples Democratic Party ko to sipo lọ sinu ẹgbẹ Apc.
Lati ijọba ibilẹ iwọ oorun Imo lo ti wa ti o si jẹ pe ẹkun idibo rẹ lo ni ijọba ibilẹ to pọ ju lọ laarin awọn ti wọn jijọ n dije.
Saa akọkọ rẹ ree lori ipo Gomina to si n gbero lati tẹsiwaju nipo yi to ba fi le jaweolubori ninu idibo to n bọ lọna.
Gbogbo rẹ dabi ẹni pe o ṣeeṣe ko ribi di ipo yi mu lẹẹkan si amọ awọn ipenija to n koju naa ko ṣe fọwọ rọ danu.
Lara rẹ ni pe aabo to mẹhẹ ni ipinlẹ rẹ ti ọpọ awọn abule ati ileto ti di ahoro nitori bawọn unknown gunmen ti ṣe gba ilu kan.
Labẹ ijọba Uzodinma, ọpọ awọn eeyan lo ti di ẹni to sa nilu tori ti aabo mẹhẹ.
Orin ti awọn alatako rẹ si n kọ lẹnu ree wi pe ki wọn dibo yọ kuro nitori pe ko kajuẹ lati ṣeto aabo to peye.
Samuel Anyanwu PDP

Oríṣun àwòrán, Facebook/Samuel Anyanwu
Yatọ si pe o n dupo Gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Sẹnẹtọ Samuel Anyanwu ni akọwe agba ẹgbẹ naa jakejado Naijiiria.
Lati igba to darapọ mọ ẹgbẹ Pdp ko fi ijọ kan kuro lati lọ si ẹgbẹ mii.
Ninu awọn oludije o sunmọ kawọn kan sọ pe oun lo ni irir agbo oṣẹlu julọ ninu awọn oludije yoku.
Idi si ni pe o ti ṣe alaga ijọba ibilẹ,aṣofin ile aṣofin ipinlẹ,sẹnẹtọ ati eekan ninu ẹgbẹ.
PDP to jẹ ẹgbẹ rẹ lawọn onwoye sọ pe o yẹ ko jẹ anfaani nla fun lati le fi ja ipo gba mọ Uzodinma lọwọ.
Bo ti lẹ jẹ wi pe ẹgbẹ naa pẹka kaakiri ipinlẹ Imo ti wọn si yi lẹnu lati gba ipo Gomina lọwọ APC, ohun kan lawọn eeyan ko dunnu si pe Samuel Anyanwu ṣe ti eyi si le ṣe akoba fun ninu idibo.
Awọn kan sọ pe awọn ko dunnu si bo ṣe gba tikẹẹti oludije ipo Gomina labẹ asia Peoples Democratic Party mọ Emeka Ihedioha lọwọ.
Ikunsinu yi lawọn kan sọ pe o mu ki awọn ọmọ igbimọ alasẹ meje fi ẹgbẹ silẹ lọ darapọ mọ Uzodinma.
Bi wọn ṣe n sọ eleyi naa lawọn alatilẹyin rẹ n sọ pe o ni awọn eekan inu ẹgbẹ Apc to n gbe lẹyin rẹ lati gba Uzodinma danu ninu idibo.
Awọn wọnyi ni ohun to ku kan ni ki Inec ma gbe lẹyin ẹnikankan ninu idibo ki o si jẹ ki ẹni ba ni ibo to pọjulọ gbe igbaoroke.
Labour Party Achonu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Athan Achonu
SẹnẹtọAchonu ni ẹni kẹtaa ti ohun na jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Inu ẹgbẹ PDP lo ti kuro lati lọ du tikẹẹti oludije ipo Gomina labẹ asia Labour Party.
Ilumọọka oloṣelu ni ti inagijẹ rẹ a si maa jẹ''One Arm General''
Ninu awọn oludije mẹta to lewaju ohun lawọn eeyan sọ pe o ni ipin idokoowo julọ ni ipinlẹ Imo.
Wọn ni o ṣe idasilẹ awọn oko agbẹ igbalode lati le fi jẹ ki eto ọrọ aje ipinlẹ naa burẹkẹ si.
Lati nkan bi ọdun mejila sẹyin ni Achonu sọ pe wọn ti gba ẹun idibo rẹ iyẹn Imo North kuro lagbo oṣelu ati ipo Gomina.
Okigwe lo ti wa ibi si ni Gomina tẹlẹ Ikedi Ohakim ti ile ẹjọ ko jẹ ki o pari saa keji rẹ lori oye lọdun 2011.
Ọpọ lo dabi ẹni pe wọn fẹran rẹ laarin araalu ti o si le lo ifẹ tawọn araalu ni si ẹgbẹ Labour Party naa lati fi de ipo Gomina.
Ṣugbọn kan to wa nibẹ ni pe ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ Labour Party le ṣe akoba fun.
Yoruba ni bi ogiri o lanu alangba ko le wọ ibẹ.
O le jẹ ifasẹyin fun Achonu ti awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ko ba ṣe rawọn lọkan.
Idibo ipinlẹ Imo yoo waye lọjọ Kọkanla oṣu Kọkanla.
O wa lara awọn idibo ti ko bọ si asiko idibo gbogboogbo ti ajọ Inec n dari ni Naijiria.
Awọn ipinlẹ mii ti wọn yoo ti yan Gomina tuntun ni Kogi ati Bayelsa .












