Makinde kéde ẹ̀kúnwó owó fún àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Ìpínlẹ Ọ̀yọ́

Aworan Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ti fọwọsi sisan owo toto ẹgbẹrun mẹdọgbọn naira fun awọn oṣiṣẹ ati ẹgbẹrun mẹdogun naira fun awọn oṣiṣẹ ifẹyinti gẹgẹ bi afikun owo iranwọ ipinlẹ naa pese.

Gomina Makinde ṣeleri wi pe owo naa yoo di sisan ninu oṣu yii ti wọn yoo si gba fun oṣu mẹfa titi ti ekunwo yoo fi de ba owo awọn oṣiṣẹ kaakiri orilẹ-ede yii.

Makinde sọ ọrọ naa nigba ti akọjọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ati awọn oṣiṣẹ fẹyinti ṣe iwọde si ile iṣe ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Agodi.

Makinde nii afikun owo iranlọwọ naa yoo mu ki owo oṣu awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Oyo le si pẹlu billionu meji naira.

O rọ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Oyo lati farada akoko yii, nitori wi pe ijọba ipinlẹ Oyo ati ijọba apapọ yoo muu igbaye gbadun awọn oṣiṣẹ orilẹ-ede yii lọkunkundun.

Awọn aṣoju ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ to wa nibi ikede naa ni Comrade Kayode Martins (NLC), Comrade Bosun Olabiyi (TUC), Comrade Olaonipekun Oluwaseun (JNC Public Sector).

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Makinde sọ pe gbogbo oṣiṣe lo maa gba owo naa

O ni awon osise feyinti yoo gba ẹgbẹrun mẹ\dogun nigba ti awọn oṣiṣẹ oo gba egbẹrun mẹẹdọgbọn.

O ni lati owo oṣu kẹwaa ni wọn yoo bẹrẹ si ni gba a

O ni won yoo san owo ti wọn je awọn osise laarin ọsẹ meji sii.

O ni ki awọn ẹgbẹ osise bẹrẹ ifọrọjomitooro ọrọ lori ẹkunwo owo oṣu to yẹ saaju oṣu kẹta, ọdun to m bọ.