Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìdápadà owó Abacha láti ilẹ̀ Faransé

Aworan Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iyapa ẹnu lo ti bẹrẹ si nii waye lori ẹrọ ayelujara laarin awọn ọmọ ilẹ Naijiria lẹyin ti orilẹ-ede France kede pe awọn ṣetan lati da owo ti iye rẹ to aadọjọ miliọnu pọun pada fun ijọba Naijiria, eyii to jẹ lara owo ti Aarẹ Ologun Naijiria nigba kan ri, Sani Abacha, ji ko lọ sibẹ.

Bi awọn kan ṣe n kan saara si oloogbe Abacha naa ni awọn kan n beere oye ti aarẹ ologun ana naa ko pamọ.

Awọn kan tiẹ kii kuuṣẹ pe niṣe lo ko owo naa pamọ nitori ọjọ ọla Naijiria.

Awọn kan ni baba daadaa to mọ itọju ọmọ ni Abacha tori pe o pese silẹ di ọjọ ọla.

Aworan esi lori ẹrọ ayeluja
Aworan ọrọ lori ẹrọ ayelujara

Oríṣun àwòrán, X/Jay Prime

Aworan esi ori ẹrọ ayelujara

Bẹẹ lawọn kan tabuku ijọba pe inakuna ni wọn yoo na owo naa ti o ba tẹ wọn lọwọ.

Aworan esi ori ẹrọ ayelujara

Awọn kan naa wi pe ki wọn fi gbogbo owo ọun ṣe 'giveaway' fun awọn ọmọ Naijiria.

Aworan ọrọ ori ẹrọ ayelujara

Oríṣun àwòrán, X(formerly Twitter)

Ẹwẹ, eebu ni ẹlomiran bẹrẹ si nii bu Abacha.

Aworan ọrọ ori ẹrọ ayelujara

Oríṣun àwòrán, X(formerly Twitter)

Paripari rẹ ni ẹni to beere pe ṣe Abacha ko fun ilẹ Ghana ni owo kankan pamọ ni.

Aworan ọrọ ori ẹrọ ayelujara

Oríṣun àwòrán, X(formerly Twitter)

A ti ṣetán láti dá $150m tí Abacha jí kó padà fún Nàìjíríà – Ìjọba France

Abacha

Oríṣun àwòrán, X/salawueedris1

Orilẹ-ede France ti ṣetan lati da owo ti iye rẹ to aadọjọ miliọnu pọun pada fun ijọba Naijiria, eyii to jẹ lara owo ti Aarẹ Ologun Naijiria nigba kan ri, Sani Abacha ji ko lọ sibẹ.

Agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Ajuri Ngelale, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Ngelale ni Aarẹ Bola Tinubu ti kan sara si ijọba France fun igbesẹ lati da owo naa pada fun Naijiria.

Lasiko to n gbalejo minisita orilẹ-ede France fun ilẹ okeere ati ilẹ Yuroopu, Catherine Colonna, Aarẹ Tinubu kan sara si irẹpọ ati ibaṣepọ to gun rege to n waye laarin orilẹ-ede mejeji, eyii to n waye lẹyin abẹwo rẹ si France.

Tinubu ni “Adupẹ lọwọ yin fun dida owo ti Abacha ji pada, a mọ riri ifọwọsowọpọ yin lori dida owo Naijiria pada.

“A o lo owo naa fun idagbasoke Naijiria.”

Tinubu tun mẹnuba adehun ibaṣepọ ọlọgọrun miliọnu Euro fun eto ‘i-DICE’ to wa fun imọ ẹrọ ati idagbasoke ạsa ni Naijiria.

Adehun ọhun ni minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati imọ ẹrọ, Bosun Tijani buwọlu pẹlu minisita to wa lati France ni gbagede Tafawa Balewa House, niluu Abuja.

Ninu ọrọ rẹ, minisita ilẹ France naa ni Aarẹ Emmanuel Macron ti ṣetan lati jawe sobi ibaṣepọ Naijiria ati France.

O ni gbogbo ohun to yẹ lawọn ti ṣe ni liana ofin ki wọn to gbe igbesẹ lati da owo ti Abacha ji naa pada fun Naijiria.

Colonna tun gboriyin fun Tinubu lori ọgbọn ati imọ to fi n dari ajọ ECOWAS.

Lẹyin naa lo fiwe pe Aarẹ Tinubu lati darapọ mọ ipade Paris Peace Forum ti yoo waye laipẹ.