Ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè Naijiria buwọ́ lu àbádòfin àfikún owó ìṣúná N2.18trn

Oríṣun àwòrán, Wikipedia
Ile aṣofin agba ati kekere ni Naijiria lo ti jumọ fọwọ si afikun owo iṣuna to le ni tiriliọnu meji naira ti aarẹ Bola Tinubu fi ṣọwọ si wọn.
Ibuwọlu yii lo waye laarin wakati mejidinlaadọta ti aarẹ fi eto iṣuna naa ṣọwọ sile aṣofin ọun.
Ile aṣofin mejeeji lo yara si abadofin naa nitori ọrọ afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ, eto abo, eto idẹkun lori ayọkuro owo epo, atawọn nkan miran to sodo sinu rẹ.
Díẹ̀ lára àwón ohun tó wà nínú àbádòfin náà rèé
Ninu owo iṣuna tuntun ọun, tiriliọnu kan o le ọgọrun miliọnu naira yoo wa fun awọn asantusan owo, nigba ti tirilọnau kan o le biliọnu kan abọ ati ẹsun diẹ yoo jẹ owo iṣẹ akanṣe.
Lara ohun to jọju ninu abadofin naa ni sisan ẹgbẹrun marundinlogoji naira fun awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ fun igba diẹ, leyi ti iye owo rẹ jẹ igba o le mẹwa naira.
Bakan naa ni irinwo biliọnu naira wa gẹgẹ bii owo iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.
Biliọnu marun ti wọn ni yoo jẹ owo ọkọ oju omi nla tẹlẹ ni awọn aṣofin naa ti jan mọ owo ẹyawo fawọn akẹkọọ leyi to sọ iye owo naa di biliọnu mẹwa naira.
Owo ti wọn yoo fi ra ọkọ ni ọfiisi aarẹ lo din ọgọrun miliọnu ni biliọnu mẹta naira, ti owo atunṣe ile aarẹ ati igbakeji rẹ si jẹ biliọnu mẹrin ati biliọnu meji-abọ ni oloriojori.
Eto aabo ni yoo gba aarunlelẹgbẹta biliọnu naira, ti atunṣe awọn afara, to fi mọ Eko bridge, jẹ ọọdunrun biliọnu naira.
Ajọ eleto idibo, INEC, ni yoo na biliọnu mejidinlogun naira, ti igba biliọnu naira si wa fun awọn eso ayi ohun ọgbin tii yoo jẹ iranwọ fawọn agbẹ.















