Ìjìyà tó wáyé lásìkò ìmúnisìn kò ì tíì kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọba Charles ati Iyawo rẹ Camila wa lori irinajo ọlọjọ mẹrin si orilẹede Kenya, ni bi to ti lọ tuba fun gbogbo asise ìjọba Cononial lasiko ti Kenya wa labẹ Ilẹ UK.
O to ẹgbẹrun mẹwaa eeyan to jade laye lasiko naa, ti awọn mii si fara ko ọpọlọpọ ifiyajẹni lasiko ti Ija Mau Mau lọdun 1950, eyi to jẹ ọkan lara ìjà ti itẹjẹ silẹ ti waye gan.
Lọdun 2013, Ilẹ Gẹẹsi ni awọn kabamọ, ti wọn san owo tótó £20m($24) fun ẹgbẹrun marun-un eeyan sugbọn awọn eeyan kan ni eyi ko de ibi to yẹ ko de.
Ọkan lara awọn eeyan nani iya aadọrun ọdun, Agnes Muthoni.
Agnes mu wa de itẹ oku to wa ni ile rẹ ni Shamata ni aarin orilẹede Kenya.
O fa awọn koríko to wa lẹgbẹ saare ọkọ rẹ tu. Elijah Kinyua jade laye ni bi ọdun meji sẹyin ni ẹni ọdun mẹtalelaadọrun. Bakan naa ni wọn mọ si Ọgagun Bahati, to jẹ ologun ni oun ati iyawo rẹ lasiko Ikọlu awọn ologun Gẹẹsi lọdun 1950.
Ipo Ọga ologun ni Agnes jẹ nínu ọmọ ogun lorilẹede Kenya ati Freedom Army ti wọn n pe ni Mau Mau.
Muthoni bu sẹrin bi o ṣe fi oruka igbeyawo rẹ ran wa. Wọn pade lẹyin ti ogun naa parí, ti wọn si tun wọn silẹ ni ahamọ ti wọn wa.
"O ni ti obìnrin jagunjagun ba wa laye, oun nifẹ lati fẹ ìkan lara wọn nítorí o mọ gbogbo isoro ohun ati pe ko ni pe oun ni Mau Mau."
Ogun lo sọ wọn di tọkọtaya. Koda lẹyin ti Kenya gba ominira lọwọ ilẹ Gẹẹsi, awọn tọkọtaya si n gbe pẹlu ibẹru pẹlu awọn ọmọ ogun Mau Mau mii.
Ikọ Ologun yii lo jẹ eyi ti ìjọba ko lu ni ontẹ. Ijọba ilẹ Gẹẹsi sapejuwe wọn gẹgẹ bii ikọ ọdaran to si jẹ pe awọn ijọba awarawa to gba ìjọba ko juwọ ofin naa silẹ lẹyin ominira.
"Ọmọ ẹgbẹ Mau Mau ko gbọdọ ṣepade, ẹsẹ ni," Agbẹjọro Kenya ati Oloselu, Paul Muite salaye. " O lodi sofin."
Lọdun 2003, ofin naa yí pada, ti wọn si bẹrẹ si ni foju ajafẹtọ ọmọniyan wo ẹgbẹ Mau Mau.
Ṣugbọn eyi ko tun mọ si pe awọn eeyan to wa lẹyin ominira ko mọ nípa ohun to sẹlẹ sẹyin.
"Ọpọlọpọ ọmọ ni ko mọ ijiya to waye saaju ominira orilẹede Kenya," Carolina Elkins salaye. O ṣe ifọrọwerọ lori iṣẹlẹ lọdun 1990.
Ohun to salaye jẹ ohun to ti di ilumọka loni niluu Nairobi. Ọpọlọpọ ọdọ ni ko mọ nnkan ti ẹgbẹ Mau Mau la kọja, ohun to ba wọn ní bi ọrọ aje yoo se gboro si, ti wọn si lero pe wiwa Ọba Charles yoo se anfaani.
Ọmọ -Ọmọ Muthoni, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, Wachira Githui, jẹ ọkan lara awọn eeyan to gbọ itan yìí sugbọn o kan sara si ipa mii to dara eyi ti ilẹ Gẹẹsi ṣe fun orilẹede Kenya.
" Mo n sọ ede Gẹẹsi daradara, o si wu mi lori," O salaye, to si fun pe ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni oun.
Ori opo ayelujara Kenya ma dun lasiko ti ifẹsẹwonsẹ ẹgbẹ agbabọọlu pataki ba waye ninu idije ligi ilẹ Gẹẹsi. Ọpọ awọn ololufẹ ni wọn yoo maa sọ okuta ọrọ si arawọn fun ọpọlọpọ wakati

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣugbọn pupọ ninu awọn nnkan to waye tẹlẹ tí Ọba Charles fẹ ṣe atunse si yii ni ko ki n se nnkan ti wọn jẹ ki awọn ọdọ mọ si ati pe wọn sokunkun sì araalu.
Paul Muite fẹ ki ijọba orilẹede Kenya ati Ilẹ UK ṣe ileeṣẹ tí yoo se iwadi kakari gbogbo Kenya, ti yoo si gba akọsilẹ gbogbo ohun to waye lasiko ijoba ilẹ Gẹẹsi.
Muite wa lara awọn Agbẹjọro to gbe lọ ile ẹjọ ọdun 2009, ti wọn si jare.
O ni pupọ eeyan ajafẹtọ ọmọniyan to si wa laye, ti ayẹwo Dokita fi di rẹ mulẹ otitọ ni sagbako Ifiyajẹyan yii lo ti gba owo.
Awọn yooku ni ẹgbẹ Talia, ti wọn kesi ilẹ UK pe ki wọn da orí olori Koitalel Arap Samoei. Ẹni to lewaju ilu Nandi lati tako ìjọba Ilẹ Gẹẹsi lasiko naa. Wọn tan wa si ipade alaafia kan, ti wọn si ṣekupa pa lọdun 1905.
Muite ni lati dida awọn eeyan mọ ni fopin si gbogbo wahala naa.
Caroline Elkins ni ikede pe Ọba Charles n bọ so orilẹede Kenya ko jẹ ohun babara sugbọn o jẹ ko di mimọ pe ijọba gbọdọ se ohun to tọ lati yi ìtan pada.
O ni gbogbo iwa ika tí awọn ijọba ilẹ Gẹẹsi wu ni wọn ṣe lorukọ Ọbabinrin ana. Queen Elizabeth II.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Aworan Ọbabinrin wa ni ibẹ bí wọn ṣe fiya jẹ awọn eeyan, ti wọn si n pariwo pe ki Ọlọrun da bobo Ọbabinrin."
O le ni ẹgbẹrun kan eeyan ti wọn yẹgi fun lasiko yii. Ogunlọgọ ẹgbẹrun eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ.
"Ko si ile fun wa lati gbe." Agnes Muthoni sọrọ lori ohun mu wọn dero inu igbo. Ikoko, ebi ati ojo lo n pa wa."
Ṣugbọn Muthoni ni oun setan lati gbagbe gbogbo ohun to waye.
"A ko ni ikoro ninu ọkan wa nítorí ohun to waye ti waye.
"Awọn eeyan ma dariji arawọn, ti wọn yoo sì ma gbe igbe alaafia papọ sugbọn emi fẹ ki wọn fun ni llẹ."












