Alága àjọ EFCC fòfin de mímú àwọn afurasí lóru ọ̀gànjọ́

Oríṣun àwòrán, Faceboo/Ola Olukoyede
Alaga ajọ to n ri si iwa jibiti ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii, Ọla Olukoyede, ti fofin de awọn oṣiṣẹ rẹ kaakiri ẹka wọn nipa bi wọn ṣe n fi ọwọ oru ati okunkun ko awọn eeyan ti wọn ba fẹẹ mu bii afurasi fun idi kan tabi ikeji.
Eyi waye lẹyin ti ọpọ eeyan koro oju si ajọ EFCC pẹlu bi wọn ṣe yawọ ileegbe awọn akẹkọo giga Ọbafẹmi Awọlọwọ Yunifasiti kan(OAU) n’Ile-Ifẹ, ti wọn si fọwọ ofin mu mejilelaadọrin ninu wọn pẹlu ẹsun pe wọn lọwọ ninu iwa jibiti ori ayelujara.
Ọjọruu ọsẹ yii ni Olukayọde gbe awọn ilana tuntun ti awọn ajọ naa yoo maa lo kalẹ lAbuja. O ni afurasi ko gbọdọ lo ju iye ọjọ ti ofin la kalẹ lọ.
Bakan naa ni ọga ajọ yii sọ pe aabo afurasi ko gbọdọ mẹhẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ EFCC to ba mu wọn. Ati pe bi wọn yoo ba gba iwe irinna afurasi silẹ, yoo maa wa ni ibamu pẹlu bi ẹṣẹ ti wọn ba ṣẹ ṣe le to ni.
Olukoyede pe fun fifi laakaye ati ọmọluabi ṣiṣẹ, o ni kawọn EFCC naa maa ṣe bawọn agbofinro ṣe n huwa lawọn ilẹ okeere to ti goke agba, ki wọn si maa fi ara wọn han bi ẹni to mọ ofin.
EFCC kó akẹ́kọ̀ọ́ 72 ní fásitì OAU sí àhámọ́, ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gùnlé ìwọ́de n‘Ibadan

Awọn akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo ni ilu Ile Ife (OAU) ti kede fun ajọ to n koju iwa ajẹbanu, EFCC, pe ko tu awọn akẹgbẹ wọn mejilelaadọrin to wa ni ahamọ wọn.
Eyi waye lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ajọ naa yabo ibugbe kan ti awọn akẹkọọ fasiti wa ni ita ọgba ileẹkọ naa mọjumọ Ọjọru.
Ni iwaju ileeṣẹ EFCC to wa ni iyaganku ni ilu Ibadan ni awọn akẹkọọ yii peju si, ti wọn si fariga pe awọn ko ni kuro ayafi ti EFCC ba tu awọn akẹgbẹ wọn ti wọn mu lọna aitọ silẹ.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi ifẹhonuhan awọn akẹkọọ yii jabọ pe n ṣe lawọn osisẹ ajọ EFCC duro wamu lẹnu ọna pẹlu ibọn, ti wọn si sediwọ fawọn akẹkọọ naa lati wọ inu ọgba wọn.
Lati nnkan bi ago mẹwaa owurọ lawọn akẹkọọ naa, to ba BBC sọrọ sọ pe awọn ti de ọfisi naa, ti awọn adari ajọ EFCC si kọ lati yọju si awọn.
Awọn akẹkọọ naa fariga pe iwa yiyabo ibugbe awọn akẹkọọ lodi sofin ati pe bi wọn ba tilẹ fẹ ko awọn akẹkọọ, oju mọmọ lo yẹ ki wọn wa, kii ṣe oru dudu.
Awọn alaṣẹ fasiti Obafemi Awolowo ko ti sọ nkankan lori iṣẹlẹ naa titi di akoko yii ti a n ko iroyin yii jọ.

Alukoro Ọlọpaa l‘Oyo àti asoju awọn akẹkọọ ba EFCC joko sepade
Nigba ti awọn agbofinro yoo fi de ibi ti iṣẹlẹ yi ti n waye, akọroyin wa jabọ pe alukoro ọlọpaa nipinlẹ Oyo lo lewaju wọn wa sibẹ.
Ọgbẹni Adewale Osifeso ba awọn akẹkọọ naa sọrọ, to si ni pe ki wọn yan ogun akẹkọọ laarin wọn, lati ba awọn adari ajọ EFCC ni gbolohun papọ.
Idi ti wọn fi fẹ ṣe ipade ọhun ko ye wa ṣugbọn awọn agbofinro ati awọn akẹkọọ lo jijọ wọle lati fọrọ jomi tooro ọrọ.
Awọn akọroyin ko lanfaani lati wọle kopa ninu ipade naa amọ gbogbo wọn ti jijọ wọle, ti ireti si wa wi pe wọn yoo yanju ọrọ lori awọn akẹkọọ to wa ni ahamọ naa.
EFCC ati awọn akẹkọọ ko ṣẹṣẹ maa woju ara wọn
Ninu awọn ti ajọ EFCC n tọ pinpin julọ ni Naijiria lawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga wa.
Yala lawọn tio fasiti tabi ni ile ẹkọ gbogboniṣe awọn akẹkọọ yi ni paapa awọn to n kopa ninu iwa gbajuẹ oriayelujara wa lara awọn ti EFCC a maa fi panpẹ ofin mu.
Lọpọ igba lawọn akẹkọọ yi a maa foju ba ile ẹjọ ti wọn a si ni kawọn mii da owo tabi dukia ti wọn ba gba lọwọ ẹni ti wọn lui nigbajuẹ pada.
Ninu awọn iwọde to maa n waye eyi tawọn akẹkọọ fi n fẹhonu han si bi Efcc ṣe n ko awọn akẹkọọ, ẹsun tawọn akẹkọọ a maa fikan wọn ni pe wọn n ko awọn ti ko mọwọ mẹsẹ ninu awọn.
Irufẹ iṣẹlẹ yi kii ṣe akọkọ iru rẹ to waye laarin awọn akẹkọọ ati awọn oṣiṣẹ EFCC.
Bi a ko ba gbagbe ni ilu Osogbo lọdun 2021, awọn osisẹ ajọ EFCC lọ silu Osogbo lati lọ ko awọn afurasi onijibiti, ti ọpọ eeyan mọ si ọmọ Yahoo, loru mọju.
Ọrọ kiko awọn ọmọ oni Yahoo naa da wahala silẹ nilu Osogbo fun ọpọlọpọ wakati, lasiko ti awọn ọdọ kan tawọn eeyan fura si pe wọn jẹ onijibiti ori ayelujara ti ọpọ mọ si yahooboys, dana wahala silẹ lawọn agbegbe kan ni igboro ilu Osogbo.















