Ẹ̀yin afurasí ọmọ Yahoo tẹ ṣèwọ́de, a kò ní dẹ́kun àti mú u yín - EFCC

EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti bu ẹnu atẹ lu awọn ọdọ to n ṣe iwọde lodi si ajọ naa nilu Ibadan.

Nigba ti EFCC yoo sọrọ loju opo Twitter ati Facebook rẹ, o ni oun ko ni dẹkun ati maa fi ṣikun ofin mu awọn afurasi onijibiti ori ayelujara.

EFCC sọ pe “Awọn ọmọ Yahoo jade lati ṣe ifẹhonuhan nitori pe a korira iwa jibiti ti wọn n wu.”

“Amọ EFCC yoo tẹsiwaju lati maa ṣawari, lati maa ṣe iwadii ati lati maa fi ṣikun ofin mu gbogbo awọn to ba n ṣakoba fun ọrọ aje wa."

Bẹẹ ba gbagbe, awọn ọdọ kan lo se iwọde lọjọbọ lori bi awọn osisẹ ajọ EFCC se n ju wọn si atimọle lọna aitọ.

Awọn olufẹhonuhan naa gbe iwọde ọhun lọ si ọọfisi ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni Agodi, pẹlu oniruru akọle lọwọ, ti wọn si n sọ pe o to gẹ fun EFCC.

Awọn ọdọ naa fẹsun kan ajọ ọhun pe wọn n fi ṣikun ofin mu awọn lọna aitọ lọna ati maa gba owo lọwọ wọn.

Ifẹhonuhan ilu Ibadan yii lo n waye lẹyin ọjọ diẹ ti iru rẹ ti kọkọ waye nilu Warri, nipinlẹ Delta.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìwọ́de n‘Ibadan tako bí EFCC ṣé ń kó wọn sí àhámọ́ lórí ẹ̀ṣùn àìmọ̀dí

Aworan

Awọn ọdọ ni kan nipinlẹ Oyo ti tutọ soke, ti wọn si n foju gbaa lori bawọn osisẹ ajọ to n sewadi iwa ọdaran nidi owonaa, EFCC se n ti wọn mọle lọna aitọ.

Awọn ọdọ naa, ti wọn pọ lọ bii esu lo ya wọ ile ìsẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati se ifẹhonuhan to tako isẹ EFCC naa.

N ṣe ni awọn ọdọ naa gbe igi da opopona to wọ ileeṣẹ ìjọba ìpinlẹ Oyo, ti wọn si fa sunkere fakere ọkọ ni opopona naa.

Awọn ọdọ naa si ri daju pe ko si ẹni to le wọle tabi jade kruo ninu ileesẹ ijọba lọgba Secretariat, ti ohun gbogbo si dẹnu kọlẹ nibẹ.

Bakan naa ni iwọde ọhun to sediwọ fun lilọ-bibọ ọkọ ni agbegbe Secretariat tun mu ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ waye lawọn agbegbe bii Total Garden ati Bodija.

Aworan awon to n se ifehonuhan

O le ni ogun mọto tawọn ọdọ fi se iwọde tako EFCC pẹlu iwe akọle ati orin

Koda, o le ni ogun ọkọ ayọkẹlẹ tawọn ọdọ naa wa debi ti wọn ti se iwọde ọhun, ti wọn si n kọ oniruuru orin lati tako iwa EFCC ọhun.

Bakan naa, oniruuru akọle ni wọn gbe dani eyi to n tako iwa bi awọn osisẹ se n ka wọn mọle, gbe wọn si ahamọ ati ifiyajẹni lọna aitọ.

Lara awọn akọle naa lo ni "Ko tọ fun EFCC lati maa gbe wa, ti wa mọle tabi fi iya jẹwa lori ẹsun aimọdi."

"Ẹ bá wa fofin si isẹ ajọ EFCC, awa ọdọ ko paniyan, gbe ibọn tabi fa wahala nigboro."

"Ẹ fopin si isẹ EFCC, ta ba dakẹ, iku ni."

Gbogbo awọn akọle naa si lo n tako ihuwasi awọn osisẹ to n dena iwa ọdaran nidi owona naa.

Awon to n se ifehonuhan

"Onimọ ẹrọ ni mi, n ko lu jibiti amọ ọpọ igba ni EFCC ti gbe mi satimọle tori mo jẹ ọdọ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn olufẹhonuhan ti o pe orukọ rẹ ni Samuel ni, awọn ṣe ifẹhonuhan naa nitori bi ajọ EFCC ṣe n fi ẹsun kan awọn pe awọn jẹ onijibiti ayelujara.

O ni onimọ ẹrọ ni oun sugbọn ọpọ igba ni ajọ EFCC ti ṣe ikọlu si oun nitori oun jẹ ọdọmọkunrin.

Bakan naa, ko si ẹnikẹni lati ileeṣẹ gomina ipinle Oyo to yọju sì awọn olufẹhonuhan naa titi wọn fi tuka.

"O ti su wa, se ni awọn osisẹ ajọ EFCC kan n gbe wa ninu ile wa bo se wu wọn, ti wọn si n yẹ ile wa wo lna aitọ.

Wọn ko fi iwe asẹ lati yẹ ile wa wo han wa, ti wọn si n pe wa ni ob=nijibiti lai jẹ pe a huwa Yahoo.

Ọpọ wa lo ni isẹ aje tiwa lọwọ, ti a ko si huwa ọdaran amọ se ni wọn n palẹ wa mọ tori pe a jẹ ọdọ lawujọ.

A wa n rọ ijọba lati ba wa da si ọrọ naa ko to bọ sori nitori ta ba le ewurẹ titi kan ogiri, yoo pada bu olowo rẹ jẹ"

Kii se igba akọkọ ree ti awọn ọdọ yii yoo maa se iwọde tako awọn osisẹ EFCC nitori irufẹ iwọde yii naa waye nilu Warri, nipinlẹ Delta.

A si ranti pe lọpọ igba ni ajọ EFCC maa n se afihan awọn ọdọ lọpọ yanturu pe wọn n lọwọ ninu iwa lilu jibiti ori ayelujara ta mọ si Yahoo.