Àṣìrì fọ́nrán ohùn àkásílẹ̀ nípa ìtàkurọ̀sọ láàrin aṣọ́lé tí Usifo kú sí àti Chidinma tú nílé ẹ̀jọ́

Aworan Chidinma

Chidinma Ojukwu, obinrin ti wọn fẹsun kan pe o ṣeku pa Usifo Ataga, ọga agba ileeṣẹ Super TV, yoo tun foju ba ile ẹjọ loni nitẹsiwaju igbẹjọ naa.

Losu Kẹrin ọdun 2021 ni awọn ọlọpaa mu Chidinma, aburo rẹ obinrin, Chioma Egbuchu ati Adedapo Quadri pe wọn lọwọ ninu iku Usifo.

Ojukwu ati Quadri n koju ẹsun onigun mẹjọ to da lori lilẹdi apo pọ, igunni lọbẹ, ipaniyan, ole jija to fi mọ ṣiṣe agbekalẹ ayederu iwe ẹri ile ifowopamọ.

Niwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko to wa ni TBS ni wọn ti n kawọ pọnyin rojọ.

Ẹni kẹẹta ti wọn fẹsun kan iyẹn Chioma n koju ẹsun ẹlẹẹkẹsan, tii ṣe jiji ẹrọ ibaraẹnisọrọ iPhone 7 arakunrin Usifo.

Ni ojule kọkandinlogun, opopona Adewale Oshin ni Lekki Phase 1 ni ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn yii, ti waye.

Aṣọle kede nile ẹjọ pe oun ka fọnran ohun Chidinma silẹ lori foonu lasiko ti wn dijọ n sọrọ

Lati igba ti igbẹjọ ti bẹrẹ, awọn ẹlẹri kan ti yọju sile ẹjọ lori ọrọ yi.

Ninu wọn ni ẹni to ni ile ti arakunrin Usifo ati Chidinmma Ojukwu jijọ sun si, ki isẹlẹ iṣekupani Usifo to waye. Bẹẹ lawọn oṣiṣẹ ile ifowopamọ, awọn oniwaadi ọlọpaa ati asọle ile ti iṣẹlẹ ipaniyan naa ti waye yọju lati wi tẹnu wọn.

Nigba ti igbẹjọ yii naa waye ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹrin oṣu Kẹwaa ọdun 2022, ile ẹjọ gba fọnran ohun lori foonu to waye laarin Chidinma ati aṣọ́le ile ti wọn pa Usifo si.

Abubakar Mohammed, tii se asọle naa si lo ka fọnka ohun itakurọsọ to waye laarin Chindima ati tiẹ silẹ lọjọ ti isẹlẹ ipaniyan naa waye.

Aworan Chidinma

Adajọ gba fọnran ohun ti wọn ka silẹ laarin asọle ati Chidinma wọle gẹgẹ bi ẹri

Ninu ọrọ ti wọn gba silẹ laarin awọn mejeeji naa ,aṣọle ọhun n bi Chidinma nibeere lori ẹrọ foonu rẹ, to si n da lohun.

Fọnran naa lo safihan igba ti Chidinma n beere pe ''ṣe ọkọ̀ rẹ wa nilẹ?'' ti Mohammed si da lohun pada pe ''ọkọ wo?''

Chidinma tun sọ pe ọkọ Range Rover, ọkọ ọga mi, Range Rover''

Ile ẹjọ tun gbọ nibi ti Mohammed ti n beere lọwọ olujẹjọ akọkọ naa pe, ki lo de ti ko fi ti pada wa lati alẹ ọjọ Iṣẹgun to kuro?

Idahun ti Chidinma si fọ lesi si ni pe ''Mo lọ si ipade ni''

Nigba ti Mohammed beere nipa Usifo boya o ṣi wa laye, Chidinma sọ pe o wa laye.

Adajọ Yetunde Adesanya gba ọrọ ori foonu yii wọle gẹgẹ bi ẹri to si sun igbẹjọ naa di Ọjọbọ oni.

Aworan Usifo Ataga

Oríṣun àwòrán, Usifo Ataga

Ta ni Usifo Ataga

Michael Usifo Ataga ti n dari ileeṣẹ kan Super Network Limited lati ọdun 2014 titi di igba ti iroyin iku rẹ gbode.

Gẹgẹ bi ọrọ to kọ soju opo rẹ ni LinkedIn ileeṣẹ rẹ yi n pese ere idaraya loju opo yelujara ni agbegbe Ikoyi ti wọn ni ọfisi si.

Usifo ni iyawo ati awọn ọmọ ti iroyin sọ pe ilu Abuja ni wọn n gbe.

Fasiti Benin ni Utaga ti kẹkọ jade laarin ọdun 1988 si 1995.

Ẹni aadọta ọdun nii ṣe.

Wọn ti sin oku rẹ lati ọgbọnjọ oṣu Keje ọdun 2021.

Chidinma nkọ?

Akẹkọọ fasiti Eko to wa ni ipele kẹta ni Chidinma Adaora Ojukwu jẹ.

A gbọ pe akẹkọọ nipa imọ ibaraẹnisọrọ nii ṣe.

Adugbo alagomeji ni o n gbe pẹlu awọn obi rẹ ni Yaba.

Ọmọ bibi ipinlẹ Abia ni Chidinma jẹ gẹgẹ bi ohun to sọ fawọn akọroyin.

Agbẹnusọ fasiti Eko ni lootọ ni Chidinma jẹ akẹkọọ awọn.