"Báńkì kọ̀ láti fún mi lówó mi, mo sì lọ fi ìbọn fọ láti kówó"

Aṣofin kan lorilẹede Lebanon ti fi aidunnu rẹ han si bi owo rẹ ṣe ha si banki, ti wọn si kọ lati fun ni owo rẹ. Eyi ko ṣẹyin bi awọn eniyan to le ni ogun ṣe n kọlu banki koowa wọn lati gba owo wọn to wa ni apo iṣuna banki wọn. Orilẹede Lebanon lo n koju ọrọ aje paapaa ẹka owo nina to dẹnukọlẹ.
Owo temi ati ti aburo mi to ni arun jẹjẹrẹ ni mo fipa gba ni Banki - Sali Hafiz
Eleyii si ti mu ki awọn banki gbe igi di bi awọn eniyan ṣe le gba owo wọn to wa ni apo isuna wọn. Amọ awọn araalu kan da ọgbọn si, ti wọn yoo si ṣekọlu si banki lọna ati gba owo wọn pada. Ijọba orilẹede naa ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ọhun, to si rọ awọn eniyan rẹ lati maṣe sọ ara wọn di ọdaran nipa ṣiṣe ikọlu si banki. Ọkan lara awọn to sekọlu si banki naa to jẹ obinrin ti sọ iriri rẹ fun BBC.
Sali Hafiz sọ fun BBC pe ni owo ohun ni oun lọ gba ni banki ati ti aburo oun to wa ni ile ifowopamọsi naa.

Oríṣun àwòrán, other
Mo tọrọ aforiji lọwọ awọn ti mo ja laya, amọ aburo mi wa ni ileewosan to nilo itọju arun jẹjẹrẹ
Sali Hafiz ni owo oun ni oun lọ gba ni banki ati ti aburo oun to wa ni ile ifowopamọsi naa
O si tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan to ko jinni jinni ba nile ifowopamọ naa.
‘’Mo tọrọ aforiji lọwọ awọn eniyan ti mo ja laya pẹlu ibọn ayederu to wa lọwọ mi.’’
‘’Amọ mi o lero lati fi ṣe ẹnikẹni ni ijamba’’
Mo nilo owo mi to wa ni banki naa lati fi tọju aburo mi to ni arun jẹjẹrẹ, to si n gba itọju ni’’
Awọn eeyan miran le pe mi ni ọdaran amọ ki ni mo fẹ ṣe nigba ti banki ko fun mi ni owo mi lati tọju aburo mi’’

Oríṣun àwòrán, other
Mo fẹ ra iwe, san owo ile ẹkọ awọn ọmọ mi lo mu mi fọ banki - Onibara mii
Ọkunrin miran to ṣekọlu si banki ni ọjọ kan naa pẹlu arabinrin yii ni oun gbe igbeṣẹ naa lati san owo ileẹkọ awọn ọmọ oun, ki awọn si le ra ounjẹ silẹ.
Ni orilẹede Lebanon lọwọ lọwọ, awọn eniyan ko lee gba ju irinwo dọla lọ ni oṣooṣu, eleyii to ti mu ki ebi ati iṣẹ pọ ni agbegbe ọhun.
Ijọba bu ẹnu atẹ lu gbigba owo ni banki pẹlu ipa, ti wọn si ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo foju wina ofin.
Nibayii, Sali Hafiz to ṣekọlu si banki naa ti na papa bọra, ti wọn si ti gba beeli ọkunrin to ja wọ banki ọhun lọjọ kan naa, lati gba owo rẹ.














