Ọ̀pọ̀ òkú sùn bí ajínigbé ṣe fi ìbọn da ọkọ̀ ojú omi nù torí báwọn èèyàn ṣe sá mọ́ wọn lọ́wọ́
Obìnrin àti ọmọdé 18 tó sá lọ́wọ́ ajínigbé kú sómi nígbà tí ajínígbé fi ìbọn da ọkọ́ ojú omi tí wọn wọ̀ nu

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Kò dín ní obìnrin méjìdínlógún tó fi mọ́ àwọn ọmọdé tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàm̀bá ọkọ̀ ojú omi.
Iwadi BBC fihan pe àwọn ajínigbé ló dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn náà ní ìpínlẹ̀ Zamfara, tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀, kí ọkọ̀ ojú omi náà tó dànù.
Àwọn eeyan méjìdínlógún ọ̀hún ló wà lára àwọn ará ìlú tí wọ́n ń gbìyànjú láti sá kúrò ní Birnin Wajje, ní agbègbè Bukkuyum níbi tí àwọn ajínigbé ti lọ ṣe ìkọlù.
Èèyàn mẹ́fà ni ajínigbé pa, tí wọ́n sì jí àwọn méje mìíràn gbé lọ - Osojumikoro
Nígbà tí ará ìlú náà kan ń bá ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀, ó ní ènìyàn mẹ́fà ni àwọn ajínigbé náà pa, tí wọ́n sì jí àwọn méje mìíràn gbé lọ.
Ó ní lẹ́yìn náà ni wọ́n tún ṣíná ìbọn bo ọkọ̀ ojú omi méjì èyí tí àwọn ará ìlú kan gbé, láti fi kúrò lọ́wọ́ ajínigbé náà.
Ó fi kun ìbon yínyìn náà ló fà á tí ọkọ̀ ojú omi náà fi dànù tí àwọn ènìyàn méjìdínlógún ọ̀hún sì pàdánù ẹ̀mí wọn.
Bákan náà ló ní yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n ti ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn, ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni àwọn kò mọ ibi tí wọ́n wà báyìí.
Agbẹnusọ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Zamfara náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ṣùgbọ́n kò sọ pàtó iye eniyan tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Àwọn ajínigbé náà tún ṣe ìkọlù sí ìlú Dargaje tó wà ní ẹgbẹ́ ìlú náà tí wọ́n sì jí ènìyàn mẹ́rìndínlógún gbé níbẹ̀ náà.
Ìpínlẹ̀ Zamfara jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ tó ń kojú ìpèníjà ààbò ní Nàìjíríà níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpànìyàn àti ìjínigbé ti ń wáyé.
Ọkọ̀ àwọn tó ń bọ̀ láti ibi ìgbéyàwó já sí kòtò, èèyàn 25 kú, 21 míì farapa

Oríṣun àwòrán, @narendraoffic1
O kere tan, eeyan marundinlọgbọn ti jade laye nibi ijamba ọkọ kan to waye niluu Uttarakhand, ni India.
Ijọba orilẹ-ede naa sọ pe nnkan bii ogoji eeyan lo wa ninu ọkọ akero naa lasiko to ya bara kuro loju ọna, to si wọ igbo lọ.
Eeyan mọkanlelogun ni wọn ti ri yọ bayii laaye ninu ibi ti ọkọ naa ha si lẹyin ti ikọ awọn adoola ẹmi ṣiṣe lorumọju.
Olootu ijọba India, Narendra Modi sọ ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ pe awọn ba ẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ kẹdun.
Iroyin ni, ibi ayẹyẹ igbeyawo kan ni awọn ero ọkọ ọhun ti n bọ ki iṣẹlẹ laabi naa to waye.
Ko si ẹni to mọ ohun to ṣokunfa ijamba naa, amọ awọn alaṣẹ ni iwadii ti bẹrẹ lori rẹ.
Awọn aworan to jade lati ibi ti ijamba naa ti waye ṣafihan ibi ti ọkọ akero naa wa lẹgbẹ oke nla kan, ti awọn adoola ẹmi si n gbiyanju lati doola awọn to wa nibẹ.
Awọn onimọ ti sọ pe ọpọ awakọ ni India ni kii n kọbi ara si abo awọn ẹlomiran to n lo oju popo.
Bẹẹ si ni ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to n ku lọdọdun latari iwuwasi awọn awakọ ni India, to fi mọ oju popo ti ko dara.
Ọkọ akero bọọsi wọnpọ ni India amọ ọpọ awọn awakọ lo maa n ko ju iye ero ti ọkọ naa le gba lọ, bẹẹ si ni ọpọ wọn kii kọbi ara si ofin to rọ mọ lilo oju popo.














