Ilé ẹjọ́ kótẹ́milọ́rùn dàbá ọ̀nà àbáyọ sí aáwọ̀ ASUU àti ìjọba,gbọ ohun tí wọn sọ

Aworan ile ẹjọ kotẹmilọrun

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to fi Abuja se ibujoko ti da aba elyi to ṣeeṣe ki o wa ojutu si aawọn to n waye laatrin ẹgbẹ olukọ fasiti Naijiria ati ijọba apapọ.

Aba n aa ti wọn gbe kalẹ ĺỌjọru ni pe ki wọn lọ fi tibu n nubi yanju ọrọ to wa laarin wọn lalae fi ti ile ẹjọ ṣe.

Ile ẹjọ gbe ọrọ yi kalẹ lasiko to n gbẹjọ kotẹmilọrun ti ẹgbẹ olukọ gbe wa ni itako aṣẹ ile ẹjọ to n pẹtu saawọ laarin oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ eleyio to ni ki ASUU pada sẹnu iṣẹ.

Lọjọ Kọkanlelogun oṣu Kẹsan ni ile ẹjọ yi gbe idajọ naa kalẹ ṣugbọn ASUU ni awọn ko faramọ eyi to mu ki wọn gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ.

Agbẹjọro agba to n ṣoju ASUU Femi Falana ati James Igwe to jẹ agbẹjọro agba ijọba ni peju sile ẹjọ.

Lati ọjọ Kẹrinla oṣu Keji ni ẹgbẹ ASUU ti gunle iyanṣẹlodi .

Losu kẹjọ ọdun yi ni ASUU kede iyanṣẹlodi patapata ti wọn si sọ pe ijọba ko ya si ohun tawọn n beere.

Lara nkan ti wọn lawọn fẹ ni pe ki ijọba ṣeto ti yoo mu iṣẹ ẹkọ gunrege si, ki wọn mu atunṣe ba awọn ile ẹkọ fasiti ijọba ki wọn si fun awọn alakoso fasiti laaye lati da ọrọ araawọn yanju.

Ọrọ gbogbo lori owo, eleyi naa jẹyọ ninu nkan to n fa ede aiyede laarin ijọba ati ẹgbẹ awọn olukọ fasiti yi.

Àwa ò ní máa yanṣẹ́lódì bíi ASUU - CONUA
Aworan CONUA

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lára ASUU, CONUA, ti sọ pe àwọn ni ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ láti wá ojútùú sí gbogbo àwọn ìpèníjà tó ń kojú àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Nàìjíríà.

Wọ́n ní èyí kò yọ ìyanṣẹ́lódì tí ASUU máa ń gùnlé ní gbogbo ìgbà sílẹ̀.

Alókòso CONUA, Niyi Sunmonu lọ sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀.

Sunmonu ní níṣe ló yẹ kí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì máa jà fún wíwà ní òmìnira ara wọn dípò àwọn nǹkan tí wọ́n ń jà fún báyìí.

Ó ní láti ogójì ọdún sẹ́yìn ni ASUU tí máa ń yanṣẹ́lódì láti fi bèrè fún ẹ̀tọ́ wọn lọ́wọ́ ìjọba tí èyí kìí sì so èso rere.

"Lábẹ́ onírúurú ìjọba yálà tí ológun ni tàbí alágbádá ohun tí wọ́n máa ń ṣe ní títọwọ́ bọ ìwé àdéhùn tí wọn kò ní múṣẹ."

"Ohun tí àwa rò ni wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí ASUU àti ìjọba àpapọ̀ bá tọwọ́bọ ìwé àdéhùn ló máa ń jẹ́ nǹkan pàjáwìrì nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àdéhùn náà kìí jẹ́ mímúṣẹ."

Sunmonu ṣe àfikún rẹ̀ pé ohun tí àwọn rò ni pé ó yẹ kí ìjíròrò tí máa wáyé fún ọjọ́ pípẹ́ dípò bí ìyanṣẹ́lódì ṣe máa ń wáyé ní gbogbo ìgbà.

Ó tẹ̀síwájú pé ohun tí àwọn yóò ṣe yàtọ̀ ni pé ìjíròrò ni àwọn yóò máa ṣe ní gbogbo ìgbà tí kò fi ní dàbí wí pé àwọn ń mú ìjọba ní tipátipá láti ṣe tàwọn

ASUU gba àbúrò, ìjọba Nàìjíríà fọwọ́sí ẹgbẹ́ olùkọ́ fásitì méjì míràn

MInisita fọrọ osise n fun ọkan lara awọn ẹgbẹ tuntun naa ni iwe ẹri

Oríṣun àwòrán, Ministry of labour nigeria

Ẹ ó rántí pé a ti mú ìròyìn wá ṣáájú pé Ijọba apapọ fọ ẹgbẹ awọn olukọ fasiti lorilẹede Naijiria, ASUU ka si mẹta bayii lẹyin to fun ẹgbẹ olukọ fasiti meji ni iwe ẹri ẹgbẹ oṣiṣẹ lọjọ Iṣẹgun.

Awọn ẹgbẹ olukọ meji tuntun ti ijọba apapọ ṣẹṣẹ buwọlu bayii ni ẹgbẹ awọn olukọ ẹka imọ iṣegun oyinbo nileẹkọ giga fasiti, NAMDA ati ẹgbẹ olukọ fasiti CONUA.

MInisita fọrọ osise n fun ọkan lara awọn ẹgbẹ tuntun naa ni iwe ẹri

Minisita fọrọ iṣẹ ati ijafafa ọwọ iṣẹ, Chris Ngige ṣalaye pe ẹgbẹ olukọni fasiti mejeeji yii yoo wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ẹgbẹolukọ fasiti ASUU ni.

Lati bii oṣu mẹjọ bayii ni ẹgbẹ olukọ fasiti, ASUU ti lẹnu iyanṣẹlodi, eyi ti wọn gun le lọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun 2022 lati fi ẹhonu wọn han lori ajẹẹlẹ owo ajẹmọnu ati lati beere fun eto igbayegbadun lọwọ ijọba apapọ.