Ẹ̀rí ọkàn ń yọ mí lẹ́nu ni mo ṣe fa ara mi fún ọlọ́pàá lẹ́yìn tí mo jí ₦600,135 ní ṣọ́ọ̀ṣì - Afurasí

Afurasi to ji owo ni sọọsi

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ti fi da awọn olugbe ipinlẹ naa loju pe eto aabo tó péye wa fún wọn, ti wọn sì tún kilọ fun awọn ti wọn ni erongba iwa ọdaran lati lọ kuro ni ipinlẹ naa.

 Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti Sunday Abutu lo ṣe ìkìlọ naa lọjọ abamẹta niluu Ado Ekiti lasiko ti o n se afihan awọn afurasi ọdaran kan ti wọn mu ni ipinlẹ naa.

 Awọn afurasí ọdaràn bii ogun pẹlu orisirisi eroja ti wọn ji ni ile iṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ekiti fihan awọn akọroyin.

 Ọkan lára wọn ni Opeyemi Adeniji ti o jẹ ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn ti o ti fi igba kan ri je oṣiṣẹ alaabo ni ile ijọsin ori-oke Joseph Ayo Babalola, Ikeji Arakeji ni ipinlẹ Osun.

 Lẹhin ikọwefiselẹ rẹ ni Oṣu Kẹta ọdun 2022, o gbe ìgbésẹ láti lò ji àwọn owo ọrẹ ti awọn eniyan ti dá sí ilé ìjọsìn ori-oke Joseph Ayo Babalola, Ikeji Arakeji ni ipinlẹ Osun.

"Ọkada ọrẹ mi ni mo ya lati rinrin ajo pẹlu owo ti mo ji, ti mo fi pade ọlọpaa lọna"

Awọn afurasi ọdaran

Èròngbà Opeyemi Adeniyi lati lo já ole ni ile ijọsin náà saseyọri, ti o ji owo to to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta, ati naira marundinlogoje

Ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ ọlọpa ẹba oju ona mu u ni opopona ogotun Ekiti.

 Ọpẹ́yẹmí so fun akọroyin BBC Yoruba pé oun lọ ya Okada ọrẹ oun lati rin irin ajo iṣẹ ibí náà ni.

O fikun pe emi inu oun ni ko jẹ ki ohun gbádùn leyin t'ohun kọjá àwọn ọlọpa ẹba oju ọna, t'ohun sí padà lọ bá wọn pe oun fe da owo ile ijọsin t'ohun jigbe pada.

 Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti Sunday Abutu, ti o ṣe afihan Opeyemi Adeniyi pẹlu awọn ọdaràn mokandinlogun míràn, wa rawọ ẹbe sí àwọn ará ìlú lati maa fi awọn iroyin to wulo ṣe iranlọwọ fún ile iṣẹ oloopa lati sisẹ wọn dáadáa.

 Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Opeyemi ati awọn afurasi ọdaràn to ku, ni wọn yoo kò lọ sí ilé ẹjọ laipẹ.

Àkọlé fídíò, Rasheed Ladoja: Buhari kùnà láti ṣe àmúṣẹ ìlérí tó ṣe, kò tún le è rẹ́yìn Boko Haram