Ọlọ́pàá , APC tako ara wọn lórí ìkọlù níbi ìpolongo Tinubu

Oríṣun àwòrán, APC Oyo
Awuyewuye ti n waye laarin ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ati ẹgbẹ oṣelu APC lori ohun to ṣẹlẹ nibi iwọde ipolongo idibo APC to waye ni ilu Ibadan.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ikọlu to waye si arakunrin kan to wọ aṣọ ẹgbẹ oṣelu APC ko ṣẹlẹ nibi ipolongo idibo naa, agbegbe miran ni awọn ole janduku ti ṣekọlu si ọkunrin kan.
Bakan naa ni adari awọn awakọ ni ilu Ibadan, Auxiliary ti wọn fẹsun kan pe oun lo wa nidi ikọlu naa ni irọ ni ẹgbẹ oṣelu APC pa mọ oun.
Amọ ninu ọrọ rẹ, Oludije fun ipo gomina lẹgbẹ osẹlu APC, Teslim Folarin to dari iwọde fun Asiwaju Bola Tinubu naa ni, ko si otitọ ninu ọrọ ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ.
‘’Awọn ole janduku lo sẹkọlu si Chukwuemeka Okoro to wọ asọ APC’’
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ni iwadii ti awọn ṣe fi idi rẹ mulẹ pe ko si ikọlu to waye si awọn oluwọde fun Tinubu ni ilu Ibadan lasiko iwọde wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii awọn ni arakunrin Chukwuemeka Okoro ko si nibi iwọde naa nigba ti wọn yinbọn fun, ati wi pe o ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye fun wọn.
Ninu ọrọ rẹ, wọn ni Okoro salaye bi awọn ole janduku ṣe wọnu ọkọ to n gbe oun lọ si ibi iwọde naa, ti wọn si gbe oun lọ si agbegbe ti oun ko mọ.
Okoro ni awọn ole ọhun gba ọkada oun, ti wọn si yinbọnm fun oun.
O ni awọn ole naa dibọn bi ẹni pe wọn fẹ sanwo gun ọkada oun lati lọ si ibi iwọde ọhun to waye ni Oke-Ado ni Ibadan.
Chukwuemeka Okoro ti adigunjale kọlu sọ bi isẹlẹ naa se waye
O ni oun naa wọ aṣọ APC ti adari APC lobinrin nipinlẹ Oyo sọ, Adora Ngozi Chukwu to fẹ ran oun lọwọ.
‘’Awọn ole meji naa wọ ọkada mi amọ nitori mi o mọ ọna ni Ibadan nitori alejo ni mi, ni wọn ṣe ni wọn yoo mu mi mọ ọna.’’
Amọ aarin awọn ole ni wọn mu mi lọ, ti wọn si na mi gidigidi, asiko ti mo gbiyanju lati sa asala fun ẹmi mi, ni wọn yin ibọn fun mi.’’
Awọn ara adugbo ti wọn doola ẹmi ni ni wọn gbe mi lọ si ileewosan labele nibi ti wọn ti yọ ọpọlọpọ ọta ibọn ni ẹṣẹ mi.’’
‘’Nibẹ ni mo ti pe arabinrin Ngozi ti wọn si gbe mi lọ si ileewosan fun itọju amọ mi o tii sọ fun Folarin Teslim oun to ṣẹlẹ gan gan si mi, amọ maa fi to ni eti.’’
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn pese aabo to peye lasiko iwọde naa nitori naa ko si ohun to jọ ikọlu nibi iwọde ọhun.
''Irọ ni ọlọpaa n pa, a ni aworan ati fidio to ṣafihan ikọlu si wa’’
Amọ ẹgbẹ osẹlu APC nipinlẹ Ọyọ ti rọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa lati ṣe iwadii wọn finifini lori iṣẹlẹ to waye nibi iwọde ọlọgọọrọ naa.
Teslim Folarin to dari iwọde naa ni awọn ko di ẹbi ru ọlọpaa amọ ki wọn ma ṣatilẹyin fun awọn to fẹ da omi alaafia ilu ru saaju ati lasiko idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọdun 2023.
Folarin ni kii ṣe awọn adigunjale lo ṣe kọlu si iwọde wọn amọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ti Auxiliary ṣe adari fun lo ṣekọlu si wọn.
O fikun un pe Arakunrin Emeka Okoro ti wọn ṣekọlu si n ṣagbatẹru awọn alatilẹyin Tinubu tii kii sẹ ọmọ ilu amọ ti wọn wa lati okeere.
Elomiran ti wọn tun ṣekọlu si ni arakunrin Tayo Oyelola, ti wọn si sa ni ada nibi iwọde naa
Awọn miran ti wọn tun ṣekọlu si ni Mukaila Lawal, Usman Adebayo, Emmanuel Akinbode ati Ridwan Gberu.
Ọlọpaa, ẹ ṣiṣẹ yin bi iṣẹ - APC
Lai fa ọrọgun, a ni aworan ati fidio to ṣafihan bi ikọlu naa ṣe waye, ti awọn ọmọlẹyin wa si ri Auxiliary nibi ikọlu naa
A n rọ ọlọpaa lati mu eto aabo lọkunkundun saaju idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọdun to n bọ.
Bakan naa ni a n kesi awọn ẹṣọ alaabo miran toku lati ṣewadii finifini ki wọn si fi awọn to ṣe ikọlu naa jofin
Nitori kii ṣe igba akọkọ ni yii ti awọn to n ṣekọlu yii ti ma n da wahala silẹ ṣaaju idibo, ti wọn si maa ṣekọlu si awọn to ba ti tako ẹgbẹ oṣelu wọn.
Jàǹdùkú kọlu olùwọ́de APC n‘Ibadan, Folarin, Auxilliary ń nàka àlébù síra wọn

Oríṣun àwòrán, Other
Lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe iwọde ipolongo lọjọ Iṣẹgun kaakiri awọn agbegbe kan ni ilu Ibadan, iroyin ti jade latọdọ awọn ololufẹ oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu naa, Sẹnetọ Teslim Fọlarin.
Folarin ni awọn janduku kan kọlu awọn oluwọde naa lasiko ti wọn fi n wọde ipolongo ibo fun Asiwaju Bola Tinubu, tii se oludije sipo aarẹ fẹgb oselu APC.
Iroyin sọ pe ọkọ lawọn janduku naa gun de ọdọ awọn oluwọde naa, ki wọn to kọlu wọn lọjọ Isẹgun ti iwọde naa waye nilu Ibadan.
Amọ ṣa, Teslim Fọlarin ti na ika si ọdọ gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde pẹlu aṣiwaju ẹgbẹ alakoso gareeji ọkọ nipinlẹ naa, PMS, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ mọ si Auxilliary.
O ni awọn mejeeji yii lo duro gẹgẹ bi iromi to lu fun awọn janduku naa.
Auxilliary lo lewaju ikọlu awọn janduku naa - Teslim Fọlarin
Ninu atẹjade kan eyi to fi sita lọsan ọjọ Iṣẹgun, Teslim Flarin ni awọn ololufẹ oun lo fara ṣeṣe lasiko ikọlu naa.
O ni ohun to ku diẹ kaato leyi ati pe iwa ipa to lee da omi alaafia ni awọn ọmọ ọlọkọ ero PMS naa hu.
O ni lati ẹyin ni awọn janduku naa ti kọlu awọn ero to n wọde ọhun bi o tilẹ jẹ wi pe iwaju lohun wa.
“Auxilliary gangan lo ṣiwaju awọn janduku naa lagbegbe iyana Labiran ni ati maa lọ si ọna Ọja Oje nilu Ibadan.”
Ibanilorukọjẹ lasan lẹsun ti APC n fi kan Auxilliary -PMS
Amọṣa, alukoro fun ajọ PMS nipinlẹ Ọyọ, Ẹmiọla Jẹlili ti sọ pe irọ funfun balau ni ẹsun ti wọn fi n kan ẹgbẹ naa.
Ajọ PMS ni ara ọna lati ta epo si aṣọ ala alaga ajọ naa ni.
“O ti di iwa ati iṣe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ lati maa da orukọ Auxilliary nigbakugba ti wọn ba ti jade lati saa le e ba a lorukọ jẹ.
O ni alaafia ilu lajọ naa wa fun ati wi pe bi eto akoso ọkọ akero nipinlẹ Ọyọ yoo ṣe kẹsẹjari lawọn n lepa bayii kii ṣe ọrọ wahala abẹnu to n waye lẹgbẹ oṣelu APC.
APC Oyo ló dá àṣà 'Èmi ló kàn' sílẹ̀, ọ̀dọ̀ wa ni Tinubu ti gbé àṣà náà - Alága APC Oyo

Ipinlẹ Ọyọ ni oludije fun ipo aarẹ Naijiria lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti mu ọrọ akọmọna rẹ “Emi lo kan” APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nipinlẹ Ọyọ.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ, Isaac Ajiboye Ọmọdewu lo sọ eyi lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan sewọde lati polongo ibo fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nipinlẹ Ọyọ.
Iwọde ipolongo alaafia naa to waye ni owurọ ọjọ Iṣẹgun bẹrẹ niwaju olu ile ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọyọ.
Iwọde naa si lo gbe wọn de agbegbe Oke-Ado, Ibadan eyi to tun fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lanfani lati ṣe igbọwọle itagbangba fun awọn oludije ti ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ lawọn ipo oṣelu gbogbo to wa fun didu lasiko eto idibo apapọ to n bọ lọdun 2023.
"Tessy lo kan ni akọmọna APC Oyo, ki Tinubu to maa lo Emi lo kan"
Bi o tilẹ jẹ wi pe aifarahan awọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa kan nibi iwọde ipolongo naa ṣi n tọka si ina aawọ to n jo laarin ẹgbẹ naa, sibẹ awọn eekan oloselu kan yọju.
Lara wọn ni oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Teslim Fọlarin, Sarafadeen Ali, Fatai Buari, Akin Alabi ati Lamiju Akala.
Ọmọdewu ni oludije sipo gomina nipinlẹ naa, Teslim Fọlarin lo kọkọ bẹrẹ aṣa lilo akọmọna “Tessy lo kan”.
O ni eleyi to ni o di ilumọọka pẹlu Aṣiwaju Bọla Tinubu bayii, amọ o ni ọdọ awọn ni ipinlẹ Ọyọ ni Tinubu ti ya ọrọ naa lo.

Ninu ọrọ tirẹ, Teslim Fọlarin to n dije fun ipo gomina nipinlẹ Ọyọ rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa, lati tubọ tẹmpẹlẹ mọ wiwaasu ihinrere nipa ẹgbẹ oṣelu naa fun awọn oludibo.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ko si ẹni to lee halẹ mọ APC mọ ni ipinlẹ Ọyọ.
Awon Alátìlẹyìn náà to gbé àwọn káàdì pẹ̀lú oríṣiríṣi àkọlé bíi: “Awa lokan”; "Jagaban lokan"; "Tessy lokan", "Dibo fun Tinubu" ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Alaga ẹgbẹ oselu APC ni ipinle Oyo, Isaac Omodewu ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu yoo ri gbogbo ibo ipinlẹ lẹkunrẹrẹ.













