"Ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ rèé bí Tinubu ṣe padà dé láti pàwọn ọ̀tá lẹ́nu mọ́"

Tinubu nigba to n sokale ninu baalu

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Ṣe ni ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú APC bí olùdíje sípò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú náà, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ṣe padà dé sí Nàìjíríà láti ìlú London.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti àwọn alátìlẹyìn Tinubu ló péjú pésẹ̀ sí pápákọ̀ Òfurufú Nnamdi Azikiwe ìlú Abuja lánàá ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹfà oṣù kẹwàá ọdún 2022, láti kí Tinubu Káàbọ̀ padà sílé.

Nígbà tí Tinubu fi ṣe ìrìnàjò lọ sí ìlú Ọba, onírúurú awuyewuye ló wáyé, tí àwọn ènìyàn tilẹ̀ ń sọ pé òjòjò ń ṣe Ògún Tinubu àti pé ó lọ gba ìtọ́jú ní ìlú London ni.

Àwọn awuyewuye yìí mú kí àwọn alátìlẹyìn Tinubu máa fi oríṣiríṣi àwòrán àti fídíò síta láti ṣàfihàn pé kokoko báyìí ni ara ọta Tinubu le.

Igbákejì Tinubu, Kashim Shettima ló ṣáájú ikọ̀ tó lọ pàdé Tinubu.

Wọ́n rò bí kò ní dé ṣùgbọ́n Ọlọ́run pá àwọn ọ̀tá lẹ́nu mọ́ - Shittu

Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀, to tún jẹ́ adarí ìpolongo Tinubu-Shettima, Adebayo Shittu ní èrò tó ya pàdé Tinubu ní pápákọ̀ òfurufú ti pa àwọn ọ̀tá lẹ́nu mọ́.

Shittu ní àwọn kan ti rò wí pé Tinubu kò ní padà dé sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mọ́ ni.

Ó ní tó bá tilẹ̀ jẹ́ pé Tinubu lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ gba ìtọ́jú ní tòótọ́, kò yẹ kí gbogbo awuyewuye náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.

O fikun pe fídíò eré ìdárayá tí Tinubu fi síta àti ìpadàbọ̀ rẹ̀ yìí tí fi òpin sí oríṣiríṣi ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ.

Bákan náà ni ẹlòmíràn tó jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ ìpolongo Tinubu, Biodun Ajiboye sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé òun kò mọ ìdí tí ẹjọ́ fi pọ̀ lórí pé Tinubu ti padà sílé.

Ó wá ń bèèrè pé ṣe àwọn ènìyàn rò pé Tinubu kò ní padà dé ni?

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ báyìí tí Tinubu tí padà sílé?

Ajiboye tẹ̀síwájú pé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ tí Tinubu jẹ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni iṣẹ́ ìpolongo ètò ìdìbò ti bẹ̀rẹ̀.

Ó fi kun pé láti alẹ́ ọjọ́bọ̀ ni iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ fún Tinubu.

Bákan náà ni agbẹnusọ ikọ̀ ìpolongo fún ipò Ààrẹ Tinubu nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bayo Onanuga ní kò dá òun lójú bóyá ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí tí àwọn fẹ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo wọn yoo waye.

Onanuga ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ló ti wà nílẹ́ fún Tinubu bo ṣe ti padà dé sí Nàìjíríà.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ní Tinubu yóò mú ìgbé ayé rọrùn fún gbogbo ènìyàn tó bá di Ààrẹ Nàìjíríà.

Sanwo-Olu ní gbogbo ìpèníjà tó ń kojú àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn obìnrin ni Tinubu yóò wá ojútùú sí.

Ó ní àyípadà tí yóò sọ ìgbé ayé àwọn ènìyàn di ọ̀tun ni Tinubu yóò pèsè tó bá di Ààrẹ Nàìjíríà.

Àlàyé rèé lórí fídíò Tinubu tó jáde níbi tó ti ń wa kẹ̀kẹ́ - Keyamo

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialabat

Festus Keyamo, to n gbẹnusọ fun igbimọ ipolongo oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti sọ pe oun ko mọ mi ibi ti Tinubu wa.

Keyamo lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels.

O ni oun ko gbagbọ pe aisan lo mu ki eekan oloṣelu naa rinrinajo to lọ.

"Ki i ṣe aisan lo gbe Tinubu kuro ni Naijria"

Agbẹjọro ọhun ni awọn oni mọnafiki lo n mọọmọ jẹ ọrọ ibi ti Tinubu wa lẹnu nitori ibo ọdun to n bọ. Gẹgẹ bii ohun to sọ, ariwo Tinubu nikna ni wọn maa n pa amọ wọn ko sọ ohunlohun nipa oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, nigba ti oun naa lọ siluu dubai.

O ni “Oludije wa ko si ni Naijiria lọwọ yii, mi o si le sọ ibi to wa, amọ mo mọ pe o maa pada si Naijiria laipẹ bo tilẹ jẹ pe mi o le sọ akoko ti yoo pada wa.”

“Kii ṣe aisan lo gbe Tinubu kuro ni Naijria, mi ọ mọ nnkankan nipa iyẹn, bakan naa, irọ nla ni pe ara Tinubu ti ko ya ni ko tii jẹ ka bẹrẹ ipolongo.”

"Iṣe Tinubu ni lati maa wa kẹkẹ, ko ṣe fidio tori awọn alatako"

Nigba to n dahun ibere lori fidio Tinubu to fa ori ayelujara ya laipẹ yii, nibi to ti n wa kẹkẹ, Keyamo ni iṣe Tinubu ni lati maa wa kẹkẹ, kii ṣe pe o lo fidio naa lati fidi rẹ mulẹ pe oludije naa wa laaye.

Keyamo ni “Awọn to sunmọ Tinubu mọ pe o fẹran lati maa gun kẹkẹ... a ko ṣe ohunkohun nitori ẹgbẹ alatako.”

“Gbogbon wa la mọ pe oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar maa n lọ si Dubai ni gbogbo igba, mi o tii ri ki ileeṣẹ iroyin kankan maa ṣe iwadii ohun to n lọ ṣe nibẹ.”

“Igbakugba ti Atiku ba rinrinajo, ko si ẹni to maa n ranti rẹ ayafi to ba pada si Naijiria.

Wọn mọ pe Tinubu to gbangba sun lọyẹ, ohun lo jẹ ki wọn maa tẹnumọ ọrọ rẹ ni gbogbo igba.”