Àlàyé rèé lórí ìdí tí MC Oluomo ṣe sún ìwóde ‘’5 milion March’’ fún Tinubu síwájú

Oríṣun àwòrán, MC Oluomo/Instagram
Alaga igbimọ to n ṣe àkóso awọn ibudokọ nipinlẹ Eko, Alhaji Musiliu Akinsanya ti gbogbo eniyan mọ si MC Oluomo, ti kede pe oun ti sun iwọde ti oun fẹ ṣe fun ìpolongo ibo fun Tinubu siwaju.
Iwọde naa lo pe ni iwọde oni miliọnu marun eeyan eyi to wa lati ṣe atilẹyin fun oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Kazeem Shettima.
Saju ni Mc Oluomo ti kede pe iwọde naa yoo waye ni Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
Papa isẹre Teslim Balogun ni agbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, si lo ti kede saaju pe iwọde naa yoo ti waye.
Idi ti mo fi wọgile iwọde fun Tinubu ree...
Ni oju opo Instagram rẹ ni MC Oluomo ti kede igbeṣẹ ati sun iwọde naa siwaju.
Ninu ikede naa lo ti ni awọn yoo jẹ ki awọn eniyan mọ igba ti iwọde naa yoo waye laipẹ.
O ni idi ti awọn fi wọgile iwọde naa ni pe ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu APC yoo gbẹrasọ ni ọjọ kẹwaa, osu kẹwaa ti awọn ni lọkan lati ṣe iwọde tẹlẹ.
Bakan naa ni lo fikun un pe oun yoo fi ọjọ tuntun ti iwọde naa yoo waye sita fun awọn araalu.
MC Oluomo wa dupẹ lọwọ awọn ololufẹ ati alatilẹyin rẹ fun igbọraẹniye wọn lori ayipada naa.
Bakan naa lo tun tọrọ aforiji lọwọ awọn ti wọn ti n reti iwọde naa pe ko waye ni ọjọ ti wọn fi si tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, kingmcoluomo/Instagram
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Orin kó sí ìjà mọ làwọn aláṣẹ àti Gómìnà APC n kọ lẹyìn ìpàdé lórí ìpolongo ìbò Tinubu

Oríṣun àwòrán, APC Twitter
Ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe awọn adari ẹgbẹ oselu naa ti yanju ọrọ lori aawọ to n ṣẹlẹ lori yiyan awọn ti yoo jẹ ọmọ igbimọ ipolongo oludije ipo aarẹ wọn Bola Tinubu.
Ni nkan bi ọjọ meloo kan sẹyin ni orukọ awọn kan jade gẹgẹ bi awọn ti yoo jẹ ọmọ igbimọ ipolongo Tinubu ti eleyi ko si dun mọ awọn Gomina ẹgbẹ naa ninu.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ awọn Gomina ko dunnu si pe o ko iyan wọn kere nipa yiyan awọn to wa ninu igbimọ ti wọn si ni awọn eeyan ti wọn ko si ninu igbimọ naa.
Ipade ti wọn ti yanju ọrọ yi waye lonii nibi ti olori awọn Gomina ẹgbẹ naa Gomina ipinlẹ Plateau Simon Lalong lewaju nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu alaga ẹgbẹ APC Adamu Abdullahi.
Nibo ni wọn fẹnu ọrọ ko si?
Iroyin taa gbọ ni pe ipade yi gba ọpọ wakati ṣugbọn aṣẹyinwa aṣẹyinbọ awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ APC ati awọn aṣaaju igbimọ ipolongo Tinubu to fi mọ awọn Gomina sọ pe awọn ti yanju ọrọ naa.
Alaga ẹgbẹ awọn Gomina APC Lalong ati Gomina ipinlẹ Kebbi Atiku Bagudu sọ fun BBC pe ko si wahala mọ:
''aṣiṣe waye, aṣiṣe naa si ni pe ọkan lara awọn to n ba ẹgbẹ ṣiṣe gbe iwe orukọ awọn ọmọ igbimọ ipolongo jade ko to di pe iṣẹ pari lori rẹ''.Ẹ mọ pe wọn ni lati ko orukọ yi jọ ki wọn to gbe jade.A ti yanju ọrọ yi,Kii ṣe ede aiyede kan to lagbara.''
Lori ifarajin wọn lati tubọ pawọpọ ṣiṣẹ fun iyansipo Bola Tinubu awọn Gomina naa sọ pe''''A fi ifarajin wa lelẹ ati atilẹyin wa fun ẹgbẹ wa awọn olori rẹ ati oludije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ wa, Bola Ahmed Tinubu''
Orukọ eeyan irinwo le mejilelogun lo wa ninu iwe orukọ awọn ọmọ igbimọ ipolongo ibo Bola Tinubu to jade sita laipẹ yi loju opo ẹgbẹ oṣelu APC ni Twitter.
Ko pẹ si igba ti orukọ yi jade lawọn ikunsinu kọọkan bẹrẹ si ni gbori tawọn ọmọ ẹgbẹ kan si sọ pe orukọ awọn eeyan ti wọn ko si ninu igbimọ ipolongo yi.
Ko daju boya wọn yoo fi kun awọn to wa lori igbimọ yi ni tabi wọn yoo yọ orukọ awọn kan kuro.
Amọ bayi ti awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ ti ṣe ipade lori rẹ, o ṣeeṣe ki a ri iwe mi ko jade eleyi ti yoo fi ti gbogbo awọn ti ọrọ kan ṣe ninu igbimọ ipolongo Tinubu.
Ajọ eleto idibo Naijiria ti kede ibẹrẹ ipolongo idibo ọdun 2023 ṣugbọn a n gbọ pe ọjọ Kẹwaa oṣu Kẹwaa ni wọn yoo ṣe ifilọlẹ igbimọ ipolongo ibo Tinuba ati Shettima ti wọn jijọ n dije dupo labẹ asia APC.












