INEC kéde orúkọ olóṣèlú 11,077 tí yóò díje du ipò gómìnà àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ lọ́dún tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria
Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC, ti kede orukọ awọn oloṣelu ti yoo dije du oniruru ipo ninu eto idibo ọdun to nbọ.
INEC ni apapọ ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun lo fi ọrukọ oludije mẹtadinlogojilelẹgbẹrin (837) kalẹ gẹgẹ bii awọn to fẹ dije du ipo gomina ni ipinlẹ mejidinlọgbọn kaakiri Naijiria.
Bakan naa ni INEC tun ni ẹgbẹrun mẹwaa le ni ojilenigba (10,240) oloṣelu lo n dije du ipo nile igbimọ aṣofin lawọn ipinlẹ ti eto idibo naa yoo ti waye.
Alaga ajọ ọhun, Mahmood Yakubu ni awọn ti ṣetan lati ṣe ohun gbogbo to yẹ ki eto idibo naa le lọ irọrun.
Amọ o ni awọn yoo nilọ atilẹyin gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati jẹ ko ṣeeṣe.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni “Ti ẹ ko ba gbabe, nnkan bii ọsẹ melokan sẹyin ni a kede orukọ gbogbo awọn to fẹ dije du ipo Aarẹ ati ile igbimọ aṣofin l’Abuja.”
“Lonii, a oo kede gbogbo orukọ awọn ti yoo dije du ipo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni gbogbo awọn ọọfisi wa.”
“Lọwọ yii, a ti ṣe eto mẹsan an ninu mẹrinla ti a la kalẹ ṣaaju eto idibo ọdun 2023.”
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni awọn agbofinro atawọn ajọ mii, to fi mọ awọn ajọ aladani ti ọrọ kan nipa eto idibo ni Naijiria.












