Bí ọkọ mi ṣe jẹ́ alága Labour Party kò dá ṣíṣe ìpolongo tèmi fún Tinubu dúró - Foluke Daramola

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM
Gbajugbaja osͅerebinrin ni Naijiria, Foluke Daramola ti ni ipo ti oͅkoͅ reͅ dimu ninu eͅgbeͅ osͅelu Labour Party ko lee pa oun lara, peͅlu bi woͅn sͅe yan oun kun igbimoͅ ipolongo fun oludije sipo aareͅ leͅgbeͅ osͅelu APC, Ahmed Tinubu.
Foluke Daramola fi ero reͅ lede ni oju opo Instagram reͅ,leͅyin to ni aheͅsoͅ nipe oͅkoͅ oun sͅisͅeͅ fun Tinubu ni eͅgbeͅ osͅelu Labour.
Daramola ni igbagboͅ oun ni pe ki oͅkoͅ ati iyawo wa ninu eͅgbeͅ osͅelu oͅtoͅoͅtoͅ ko ba nkankan jeͅ, ti ko si yeͅ ko fa wahala abi aigboͅraeͅniye.
Laipeͅ yii ni woͅn yan Daramola geͅgeͅ bi oͅkan lara awoͅn igbimoͅ ipolongo fun Tinubu ninu eͅgbe osͅelu APC.
Amoͅ oͅkoͅ reͅ , Ezekiel Kayode Salako ni Alaga eͅgbeͅ osͅelu ‘Labour party’ ni ipinleͅ Eko, to si jeͅ alatileͅyin fun oludije sipo aareͅ leͅgbeͅ osͅelu ‘Labour Party’, Peter Obi.
Oͅkoͅ n sͅe ‘Labour Party, Iyawo n sͅe APC…

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM
Ninu oͅroͅ reͅ, Daramola ni ko si iyoͅnu nitori oͅkoͅ oun moͅ pe oun ni ifeͅ eͅgbeͅ osͅelu APC denudenu , ti ko si ni si iyoͅnu.
‘Ahesoͅ lasan ni pe oͅkoͅ mi n sͅisͅeͅ fun APC ni ipo alaga eͅgbeͅ osͅelu Labour Party, denudenu ni oͅkoͅ mi duro ti Peter Obi, ti kosi si mimi kan to le mii.’’
‘Awoͅn to moͅ oͅkoͅ mi moͅ wi pe kii sͅe oͅgagun ninu ile, o faye gba ki iyawo reͅ naa soͅroͅ, to si boͅwoͅ fun ero reͅ peͅlu.’’
‘Eyi mu ki o ni igbagboͅ ninu ero mi lati darapoͅͅ moͅ eͅgbeͅ osͅelu APC, ti ko si tako mi’’
’Ere isͅeͅ takntakun ti mo sͅe ninu eͅgbeͅ osͅelu APC ni ipo tuntun ti woͅn fi mi si nitori ti oͅmoͅ ba sͅisͅeͅ dara dara, a o tun fi isͅeͅ miran da loͅ.'
Foluke Daramola, Jide Kosoko, Saheed Balogun, Ogogo àtàwọn òṣeré tíátà míì tí wọ́n yàn sínú ìgbìmọ̀ ìpolongo ìdìbò ààrẹ Tinubu rèé

Ẹ o ranti pe a ti mu iroyin wa pe bi ipalẹmọ eto idibo aarẹ ti n kanlẹkun dẹẹdẹ, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti gbe orukọ awọn ti yoo wa lara igbimọ ipolongo ipo aarẹ wọn jade.
Ni ọjọ Abamẹta ni wọn gbe orukọ awọn eeyan irinwo le mejilelogun naa jade ti eleyi si ti n mu kawọn ọmọ Naijiria maa sọ ero ọkan wọn nipa rẹ.
Bawọn kan ṣe n sọrọ nipa awọn ti orukọ wọn ko si nibẹ bi igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo ati akọwe ijọba apapọ Boss Mustapha to fi mọ Minisista feto ibaraẹnisọrọ tẹlẹ to si jẹ eekan ninu ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Oyo, Bayo Shittu, bẹẹ lawọn mii n ṣe ayẹwo finifini orukọ inu iwe naa ti wọn gbe jade.
Bo ti lẹ jẹ wi pe ẹgbẹ APC ti jade lati ṣalaye idi ti orukọ bii ti igbakeji aarẹ ko ṣe si nibẹ, eleyi ti awa fẹ ṣe agbeyẹwo rẹ ninu awọn orukọ yii lorukọ awọn oṣere tiata ti wọn pada wa gbe orukọ wọn jade ninu igbimọ ipolongo naa.
Awọn oṣere wo lo wa ninu igbimọ ipolongo idibo Tinubu ?

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/
Ni meni meji, a ri awọn orukọ oṣere tiata Yoruba to jẹ gbajumọ ti araalu si mọ wọn daada.
Ṣaaju ki wọn to gbe orukọ yii jade lati rii tawọn oṣere wọnyi ti n ṣe fọnran fidio atilẹyin fun Bola Tinubu ti wọn a si maa foju han pe awọn duro lẹyin rẹ bi ike.
Lara awọn oṣere tiata ti wọn gbe orukọ wọn sita la ti ri:
- Jide Kosoko
- Fathia Balogun
- Saheed Balogun
- Bimbo Daramola
- Taiwo Hassan Ogogo
- Mojisola Adewale
- Kikelomo Adeyemi
- Remi Oshodi
Wọn fi awọn oṣere yii sabẹ akoso ẹka awọn amuludun.
Akọwe igbimọ lẹka amuludun ni Jide Kosoko jẹ ni ipinlẹ Eko nigba ti Saheed Balogun si jẹ igbakeji agbẹnusọ ni Eko.
Yatọ si awọn ti o jẹ osẹre tiata ati amuludun lati iwọ oorun Guusu, wọn yan awọn miran naa lati apa ariwa ati ila oorun Guusu Naijiria bi Zack Orji, Sani Idris Moda Nuhu Abdullahi ni Kano ati awọn miran.

Oríṣun àwòrán, APCPresCC2022
Ki ni pataki igbimọ ipolongo idibo gaan?
Labẹ oṣelu awarawa awọn ẹgbẹ oṣelu a maa ṣe akitiyan lati wa ọna ti araalu yoo fi dibo yan awọn aṣoju ẹgbẹ wọn dipo ti ẹgbẹ miran.
Ninu ọna ti ofin faaye gbawọn ni ṣiṣe ipolongo idibo bi asiko ibo ba ṣe n sunmọ bọ.
Ni Naijiria, awọn to n dije dupo aarẹ paapa a maa farabalẹ ṣe akojọ orukọ awọn ti yoo di ipo orisirisi mu labẹ eto ipolongo ti o si ṣe pe orukọ yi yoo ṣafihan bi ẹgbẹ naa ba ṣe tagba de kaakiri Naijiria.
Bi wọn ṣe n mu awọn oloṣelu, bẹẹ ni wọn a maa mu awọn mii to ṣe pe wọn ni ipa kan tabi omiran ti wọn yoo ko lara eto ipolongo yii.
Ni gbogbo igba ti idibo paapa ti aarẹ ba ṣe n sunmọ si si ni awọn araalu maa n foju sọna lati wo awọn ti ẹgbẹ kọọkan yoo yan sipo labẹ igbimọ ipolongo yi.
Njẹ awọn ọmọ igbimọ ipolongo a maa gba owo fun iṣẹ ti wọn ba ṣe?
A ko ri akọsilẹ ninu iwe ofin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to sọ boya wọn yoo san owo fun awọn ọmọ igbimọ ipolongo aarẹ tabi wọn ko ni san an fun wọn.
Eyi taa mọ ni pe loore koore ni awọn igbimọ ẹgbẹ a maa yan igbimọ mii ki wọn baa le tẹsiwaju pẹlu eto ẹgbẹ wọn.
Ninu awọn igbimọ to maa n waye loore koore ni ti ipolongo idibo yi jẹ.
Labẹ ofin, ẹgbẹ funrarẹ, a maa ri owo lati ọna meloo kan bi owo ti awọn ọmọ ẹgbẹ ba da fun iṣakoso ẹgbẹ osẹlu, eyi ti ijọba ba fun wọn, eyi ti wọn ba ri lati idokoowo ti ẹgbẹ ba ṣe tabi nipa yiya owo ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ba buwọlu.
Leyi ti awọn ẹgbẹ maa n sọ fun awọn to ba fẹ ṣe iru iṣẹ yii, wọn a maa sọ fun wọn pe ifarajin lo jẹ ati pe bi wọn ba debi ṣe aṣeyọri tan, gbogbo onikaluku to kopa lati gbe ẹgbẹ de ipo naa ni yoo jẹ ninu mudunmudun to ba wa labẹ iṣejọba wọn.















