Wo àwọn òṣèré tó bá ìpèníjà kídìnrín fínra

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Àrùn tí kò gbọ́ oògùn kí Ọlọ́run má fi ṣe wá ni àdúrà tí kìí wọ́n lẹ́nu àwọn ènìyàn.
Ní òde òní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń kojú ìpèníjà ìlera kan tàbí òmíràn.
Lára àìsàn tó ń gba omijé lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn tó sì ń ṣe àkóbá fún ẹ̀yà ara ni àìsàn kídìnrín jẹ́.
Àwọn onímọ̀ ìlera nínú ìwádìí wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tó wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ní àwọn ilé ìwòsàn ńlá ní Nàìjíríà ló jẹ́ wí pé àìsàn tó jẹ mọ́ kídìnrín ló ń yọ wọ́n lẹ́nu.
Lára àwọn ohun tí wọ́n ní ó máa ń fa àìsàn kídìnrín ni omi tí kò dára, èéfí, mímú egbògi olóró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Wọ́n ní kò sí ẹni tí àìsàn yìí kò le bá jà, ìbáà ṣe ọmọdé tàbí àgbàlalgbà.
Bákan náà ni àìsàn ọ̀hún kò dá olówó mọ̀ yàtọ̀ sí tálákà, ọlọ́lá tàbí bọ̀rọ̀kìní.
Wọ́n ní àwọn mìíràn máa ń yè é tí wọ́n bá tètè mọ̀ tí àwọn mìíràn sì máa ń ba lọ tó bá ti pẹ́ lára ju bó ṣe yẹ lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré yálà nídìí iṣẹ́ orin tàbí tíátà náà ló ti lùgbàdì àìsàn búburú yìí.
Lára àwọn gbajúmọ̀ tó ti ní àìsàn yìí nìyí:
Dejo Tunfulu

Oríṣun àwòrán, Dejo Tunfulu/INSTAGRAM
Ní ọjọ́ kìíní oṣù Kẹrin ọdún 2022 ni ariwo ẹkún sọ ní agbo òṣèré tíátà Yorùbá nígbà tí títán débá gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú tíátà Adekunle Adetokunbo tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Dejo Tunfulu.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn kò mọ̀ wí pé òṣèré náà ń kojú àìlera kó tó di pé ọlọ́jọ́ dé, wọ́n ní òṣère náà ti ń bá àìsàn kídìnrín fínra fún ìgbà díẹ̀ kó tó mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ.
Ọ̀rẹ́ Dejo tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ó ti pẹ́ tí Dejo ti ṣàlàyé ìpèníjà ìlera rẹ̀ fún òun ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ bóyá ó sọ fún àwọn ẹbí àti ará rẹ̀.
Ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sọ fún òun tó bá fẹ́ lọ ra ògùn rẹ̀.
Ilé ìwòsàn ìjọba tí Dejo kú sí náà ní agbègbè Ikorodu nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n dfi síta lẹ́yìn tí Dejo dágbére fáyé ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ya ara Dejo ni kò ti ṣiṣẹ́ bó ti yẹ kí ọlọ́jọ́ tó dé àti pé “immunosuppression” ló ṣekúpa á.
Àtẹ̀jáde náà ni wọ́n fi fèsì sí ìròyìn pé àwọn fi ìlera Dejo falẹ̀ lo ṣokùnfà ikú rẹ̀.
Pásítọ̀ Ajidara

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Nínú oṣù Kẹrin, ọdún 2017 ni gbajúgbajà òṣèré Samuel Adesanya tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí pásítọ̀ Ajidara gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra.
Àìsàn kídìnrín ni wọ́n ní ó bá fínra títí ọlọ́jọ́ fi dé.
Ìyáwó rẹ̀, Atinuke Adesanya tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní ilé ìwòsàn kan ló kú sí ní ìlú Abeokuta níbi tó ti ń gba ìtọ́jú.
Ó kú ọjọ́ méjì tí Adesanya papòdà ní àwọn ẹbí ké gbàǹjarè pé àwọn nílò mílíọ̀nù méjìlá láti san gbogbo gbèsè tí wọ́n jẹ kalẹ̀ ní ilé ìwòsán tó ti ń gba ìtọ́jú.
Eedris Abdulkareem

Oríṣun àwòrán, Eedris Abdulkareem/Instagram
Gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé ni Eedris Abdulkareem tó gbajúmọ̀ fún orin “Nàìjíríà jàgàjágá” àti “Mr Lecturer.”
Ní nǹkan bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni Eedris Abdulkareem kéde pé òun ní àìsàn kídìnrín tí òun sì ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn kan ní ìpínlẹ̀ Eko.
Nínú oṣù Kẹjọ ọdún 2022 ní Abdulkareem tún fi àtẹ̀jáde kan léde tó ti ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó rẹ̀ fún bí ó ṣe fún òun ní ẹyọ̀kan nínú kídìnrín tirẹ̀ àti pé iṣẹ́ abẹ tí àwọn ṣe yọrí sáyọ̀.
Ní ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹsàn-án ló fi ìròyìn sójú òpó Instagram rẹ̀ wí pé òun ti padà sílé tí òun sì wà ní àláfíà ara.
OJB Jezreel

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀ka orin tàkasúfèé ní Nàìjíríà ṣe ti gòkè àgbà lónìí láì dárúkọ Babatunde Okungbowa tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí OJB Jezreel kò ì tíì pé.
Jezreel tó gbajúmọ̀ fún ṣíṣe ìlù sí àwọn orin ló ṣe olóòtú orin African Queen tí 2face kọ, Ìyàwó Àsìkò, Kiss me Again àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọdún mẹ́rin ló fi bá àìsàn kídìnrín fínra kí ikú tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò ní ọdún 2016.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó rẹ̀, Mabel fun ní kídìnrín kan ṣùgbọ́n kò ru àìsàn náà là tó sì papòdà lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ náà.















