Wo bí oró àkekèé ṣe le sọ ẹ́ di olówó tabua

Àkọlé fídíò, Scorpion Venon: N jẹ ó mọ pe lítà oró àkekèé kan le fún ọ ní $10m?
Wo bí oró àkekèé ṣe le sọ ẹ́ di olówó tabua
Aworan akeeke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni ẹni tí kò bá mọ ibi ti ẹgbẹ́ rẹ̀ ti n là, yóò kan sá ere asaku ni.

Ohun tá sì ń wá lọ sí Sokoto, a ṣe e àpò ṣòkòtò wa lo wa.

Fún àwa ta n la kàkà láti ṣẹ igi ọlà, ká di olówó gọbọi, ọ̀nà kan rèé ti kò la wàhálà lọ rara láti rí taje ṣe.

Bawo ni àkekèé ṣe ń sọ èèyàn di olówó?

BBC ṣe abẹwo sileesẹ to ń ṣe àyẹ̀wò kan lórílẹ̀ èdè Turkey, to ń sin àkekèé láti pa owó gọbọi.

Àwọn àkekèé yìí ni wọ́n ń sìn, ti wọn si n yọ díẹ̀ lára oro ti àkekèé kọ̀ọ̀kan ni.

Ti wọn ba si ri to lítà kan oro àkekèé, mílíọ̀nù mẹwa dọla ni wọn yoo ta a si orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà.

Níléeṣẹ́ náà, yàrá tí wọn ti ń gba oro àkekèé lee gba to Hírámù oro àkekèé méjì lojumọ.

Báwo ni wọn ṣe ń gba oro lára àkekèé kọ̀ọ̀kan?

Àpótí ńlá kan ni awọn òṣìṣẹ́ láàbù n ko awọn àkekèé naa si, ti wọn yoo si maa yọ wọ́n jáde ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti inú àpótí náà.

Wọn yóò fi ẹmuga meji mu wọn, ẹmuga yoo mu àkekèé náà ni ọrùn, tí ẹmuga kejì yoo si mu ni iru.

Asiko yii ni wọn yóò fun oro díẹ̀ jáde lára rẹ sínú síbi kan, kí wọn to da sínú ike.

Wọn yoo wa gbe pamọ láti gbe lọ sorilẹ èdè Amẹ́ríkà fún títà.

Laabu ti wọn ti n gba oro akekee

Nibo ni wọn ti ń rí àkekèé to pọ láti gba oro rẹ?

Nígbà tó n bá BBC sọ̀rọ̀, ẹni tó ní oko àkekèé náà, Metin Orenler ṣàlàyé pé lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, Iléeṣẹ́ náà ni to àkekèé ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba.

Orenler ni àwọn n sin awọn àkekèé náà nínú oko àwọn, ti wọn si n fun oro ara wọn.

O fikùn pé àkekèé kan ní tó oro miligiramu méjì, tí àwọn ba fun oro rẹ tán.

O fikùn pé àwọn ń gba to oro giramu kan lara àkekèé to to ọọdunrun tàbí irínwó.

O wa fi idi rẹ̀ mulẹ pe oro àkekèé lítà kan ní àwọn n ta ni mílíọ̀nù mẹ́wàá dọla.

Akekee

Ki ní wọn n fi oro àkekèé ṣe àbí kí ló wúlò fún?

Ìwádìí BBC fihan pe oro àkekèé olówó iyebíye yìí ni wọn n lo láti fi ṣe òògùn aporó. Bákan náà, wọn tún ń lo oro àkekèé láti fi ṣe òògùn asaraloge.

Oro àkekèé yìí naa tun wúlò láti fi pèsè oogun tó ń mú ìrora kú nínú agọ ara eeyan.

Akekee