‘’Ohun tí Tinubu fẹ́ fúnmi nìyíí ká ní mo darapọ̀ mọ́ APC...’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ni oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu fi ipo ṣenatọ lọ oun nigba ti wọn pade ni London laipẹ yii.
Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori aigbọraẹniye lẹgbẹ oṣelu PDP lọ sọ bẹẹ.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, Tinubu fi tikẹẹti ile aṣofin agba lọ oun, amọ o ni idi ti oun fi dije du ipo aarẹ ni wipe oun fẹ ipo naa, kii ṣe sẹnetọ tabi igbakeji rẹ.
‘’Mi o kii ṣe awọn ẹlomiran to ra tikẹẹti ṣẹnatọ pẹlu ipo aarẹ.’’
‘’Nitori naa ni mo ṣe kọ jalẹ fun Tinubu nigba to fi ipo ṣẹnetọ lọ mi ti mo ni mi o fẹ.’’
Ti ẹ ba to bẹẹ, ẹ le mi kuro ni PDP - Wike

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gomina ipinlẹ Rivers Nyesom Wike ti ni oun ko ko ọrọ oun jẹ lori ki alaga ẹgbẹ, Iyorchia Ayu kọ iwe fi ipo silẹ.
O ni bakan naa ni ko si ẹnikẹni ninu ẹgbẹ naa to le e yọ oun ni ipo.
‘’Bio tilẹ jẹpe ko si ẹni to gaju ẹgbẹ lọ, ẹ yọ mi ni ipo ki ẹ wa mọ bi mo ṣe jẹ.’’
‘’Ko si bi PDP ṣe le di ipo aarẹ mu ni Naijiria lai jẹ pẹ wọn fi ti ipinlẹ River ṣe.’’
‘’Bakan naa ni ko lee si ipo aarẹ lai si ipinlẹ Eko, Kano ati Rivers nibẹ, ko lee ṣeeṣe.’’
Eyi n wayẹ lẹyin ti Wike ati awọn iṣọgbe rẹ yọ ara wọn kuro ninu ikọ ipolongo fun Atiku ni ọdun 2023.
Ohun to n fa rudurudu ninu ẹgbẹ PDP ni ‘’Zoning’’
Wike ni ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣe to nipa yiyi ẹni ti yoo dije du ipo lọ si ẹkun to kan.
O bu ẹnu atẹ lu bo ṣe jẹ ariwa orilẹede Naijiria nikan ni oludije ti n wa lati ọdunbọdun ṣẹyin.
O ni wọn ro wi pe nitori ẹya ariwa pọ, ohun gbogbo gbọdọ lọ si agbegbe wọn, eleyii ti Wike ni ko boju mu rara.
‘’Nitori naa ẹgbẹ oṣelu PDP gbọdọ gbọ ohun ti a n sọ, ti alaga ẹgbẹ ba fẹran ẹgbẹ, ki o fi ipo silẹ.’’
‘’Adehun ni pe ti aarẹ ba ti wa lati ariwa Naijiria, alaga ẹgbẹ yoo fi ipo silẹ fun Guusu lati dari ẹgbẹ oṣelu PDP.’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ọyọ ṣatilẹyin fun Makinde lori iyọnipo Ayu
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Oyo ti bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ondo, Ogun ati Ekiti lori ọrọ ti wọn sọ lati tabuku gomina ipinlẹ Oyo Makinde.
Laipẹ ni Makinde fi iroyin lede pe ki Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP kọ iwe fi ipo silẹ fun ẹni ti yoo wa lati Guusu di ipo naa mu.
Amọ ẹgbẹ oṣelu PDP fi iroyin lede pe ẹka ẹgbẹ ni ipinlẹ Ondo, Ekiti ati Ogun ti ṣatilẹyin fun Ayu lati di ipo rẹ mu.
Ẹka ẹgbẹ naa ni Oyo ni eyi ko bojumu rara nitori Makinde ni aṣẹ ju gbogbo awọn to ku lọ nitori oun nikan ni gomina ni ilẹ Yoruba lati ẹgbẹ oṣelu PDP.
Nitori naa wọn ke si wọn ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, ki Ayu si kọ iwe fi ipo silẹ ni kiakia, ki ẹgbẹ oṣelu PDP le tooro.












