Amotekun àtàwọn ẹsọ àláàbò míì kò ní kópa nínú ìpolongo ìbò - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá

Aworan Ọga agba ọlọpaa ati ikọ Amotekun

Ọga fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba ti pasẹ pe ki wọn fi ofin de lilo ikọ ẹsọ alaabo Amọtekun, ESN ati awọn ẹsọ alaabo miiran to jẹ ti ipinlẹ fun iponlogo ti yoo bẹrẹ lọsẹ to n bọ.

Baba sọ eleyi nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọm adari ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja.

O salaye pe ipinu lati fi ofin de awọn ẹsọ alaabo naa lo wa lati ri pe eto idibo lọdun 2023 lọ ni alaafia kaakiri Naijiria.

O wa pasẹ fun awọn kọmisana ọlọpaa lati tẹlẹ ofin naa, ki wọn si ri pe awọn iponlogo ibo awọn ẹgbẹ oṣelu tẹle ilana ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe kalẹ.

O ni ki awọn kọmisana naa ṣe isẹ wọn bo ṣe yẹ pẹlu ofin ilana ileeṣẹ ọlọpaa tọdun 2022.

Bakan naa lo ni ki wọn ri pe eto iponlogo naa ko fa rogbodiyan kaakiri oriléede Naijiria.

“A fi da awọn ọmọ loju pe sisọ ẹmio ati dujia wọn lo jẹ wa logun pupọ.

“Eto idibo lọdun 2023 ni yoo jẹ bi idanwo fun wa sugbọn o da mi loju pe ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria koju osuwọn lati ri pe eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ.

“A fi ọkan yin balẹ nitori ileeṣẹ ọlọpaa ni ifẹ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọkan.

“Nipa bi a ṣe fẹ mu awọn nkan yi wa si imusẹ ni a fifi ofin de lilo awọn ẹsọ Amọtẹkun ati awọn ẹsọ alaabo yooku nitori ofin ko gba wọn laye lati kopa ninu ẹto idibo.

Ìjàmbá ṣolè...! Ọwọ́ tẹ afurasí adigunjalẹ̀ márùn ún lójú iṣẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, OGUN POLICE

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ni awọn ti fi panpẹ ọlọpaa mu ọkunrin marun fun ẹsun ole jija ni ipinlẹ Ogun.

Ileeṣẹ ọlọpaa darukọ awọn afurasi adigunjale naa gẹgẹ bi Umar Haruna, Abbah Yahaya, Muritala Umar, Wale Fadeyi ati Segun Olofinmade.

 Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa nigba ti awọn gba ipe pajawiri ni agọ ọlọpaa Sango ni oru ganjọ.

Ipe pajawiri naa lo ki awọn ọ̀lopaa naa gbera lọ si ileeṣẹ naa ti wọn ti n ta awọn engini ọkọ.

Adigunjale ní adari eto aabo ni ileeṣẹ naa tẹlẹ lo ran awọn wa - Ọlọpaa

Wọn ni awọn adigunjale naa le ni eeyan mẹwaa pẹlu ọkọ Mitsubishi tì wọn gbe naa.

Kete ti wọn ri awọn ọlọpaa naa ni wọn salọ amọ ti wọn ri marun un gbamu ninu wọn.

Lara awọn ti wọn ri mu naa ni wọn sọ pe adari eto aabo ni ileeṣẹ naa tẹlẹ lo ran wa wa.

Adari ẹka aabo naa ni wọn yọ ni iṣẹ ni nkan bi oṣu mẹta ṣẹyin.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọ̀paa ni iwadii ti bẹrẹ ni kikun lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa adari eleto aabo naa.